I. Kor 14:4-6
I. Kor 14:4-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹniti nsọ̀rọ li ède aimọ̀ nfi ẹsẹ ara rẹ̀ mulẹ; ṣugbọn ẹniti nsọtẹlẹ nfi ẹsẹ ijọ mulẹ. Ṣugbọn iba wu mi ki gbogbo nyin le mã sọ oniruru ède, ṣugbọn ki ẹ kuku mã sọtẹlẹ: nitori ẹniti nsọtẹlẹ pọ̀ju ẹniti nsọ oniruru ède lọ, ayaṣebi o ba nṣe itumọ̀, ki ijọ ki o le kọ́ ẹkọ́. Njẹ nisisiyi, ará, bi mo ba wá si arin nyin, ti mo si nsọrọ li ede aimọ̀, ère kili emi o jẹ fun nyin, bikoṣepe mo ba mba nyin sọrọ, yala nipa iṣipaya, tabi nipa imọ̀, tabi nipa isọtẹlẹ, tabi nipa ẹkọ́?
I. Kor 14:4-6 Yoruba Bible (YCE)
Ẹni tí ó ń fi èdè àjèjì sọ̀rọ̀, ara rẹ̀ nìkan ni ó ń mú dàgbà. Ṣugbọn ẹni tí ó ń waasu ń mú ìjọ dàgbà. Inú mi ìbá dún bí gbogbo yín bá lè máa fi èdè àjèjì sọ̀rọ̀. Ṣugbọn ohun tí ìbá dùn mọ́ mi ninu jùlọ ni pé kí ẹ lè máa waasu. Ẹni tí ó ń waasu ju ẹni tí ó ń fi èdè àjèjì sọ̀rọ̀ lọ, àfi bí ó bá túmọ̀ ohun tí ó fi èdè àjèjì sọ, kí ìjọ lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ fún ìdàgbà ẹ̀mí. Ará, ǹjẹ́ bí mo bá wá sọ́dọ̀ yín, tí mò ń fi èdè àjèjì sọ̀rọ̀, anfaani wo ni mo ṣe fun yín? Kò sí, àfi bí mo bá ṣe àlàyé nípa ìfihàn, tabi ìmọ̀, tabi iwaasu, tabi ẹ̀kọ́ tí mo fi èdè àjèjì sọ.
I. Kor 14:4-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹni tí ń sọ̀rọ̀ ni èdè àìmọ̀ ń fi ẹsẹ̀ ara rẹ̀ mulẹ̀; ṣùgbọ́n ẹni ti ń sọtẹ́lẹ̀ ń fi ẹsẹ̀ ìjọ múlẹ̀. Ṣùgbọ́n ìbá wù mí ki gbogbo yín lè máa sọ onírúurú èdè, ṣùgbọ́n kí ẹ kúkú máa sọtẹ́lẹ̀: Ẹni tí ń sọtẹ́lẹ̀ pọ̀ jú ẹni ti ń fèdèfọ̀ lọ, bi kọ ṣe pé ó bá ń ṣe ìtumọ̀, kí ìjọ bá à lè kọ́ ẹ̀kọ́. Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ará, bí mo bá wá sí àárín yín, tí mo sì ń sọ̀rọ̀ ní èdè àìmọ̀, èrè kín ni èmi yóò jẹ́ fún yin, bi ko ṣe pé mo bá ń bá yín sọ̀rọ̀, yálà nípa ìṣípayá, tàbí ìmọ̀ tàbí nípá ìsọtẹ́lẹ̀, tàbí nípa ẹ̀kọ́?