I. Kor 14:1-17

I. Kor 14:1-17 Bibeli Mimọ (YBCV)

Ẹ mã lepa ifẹ, ki ẹ si mã fi itara ṣafẹri ẹ̀bun ti iṣe ti Ẹmí, ṣugbọn ki ẹ kuku le mã sọtẹlẹ. Nitori ẹniti nsọ̀rọ li ède aimọ̀, kò bá enia sọ̀rọ bikoṣe Ọlọrun: nitori kò si ẹniti o gbọ; ṣugbọn nipa ti Ẹmí o nsọ ohun ijinlẹ: Ṣugbọn ẹniti nsọtẹlẹ mba awọn enia sọrọ fun imuduro, ati igbiyanju, ati itunu. Ẹniti nsọ̀rọ li ède aimọ̀ nfi ẹsẹ ara rẹ̀ mulẹ; ṣugbọn ẹniti nsọtẹlẹ nfi ẹsẹ ijọ mulẹ. Ṣugbọn iba wu mi ki gbogbo nyin le mã sọ oniruru ède, ṣugbọn ki ẹ kuku mã sọtẹlẹ: nitori ẹniti nsọtẹlẹ pọ̀ju ẹniti nsọ oniruru ède lọ, ayaṣebi o ba nṣe itumọ̀, ki ijọ ki o le kọ́ ẹkọ́. Njẹ nisisiyi, ará, bi mo ba wá si arin nyin, ti mo si nsọrọ li ede aimọ̀, ère kili emi o jẹ fun nyin, bikoṣepe mo ba mba nyin sọrọ, yala nipa iṣipaya, tabi nipa imọ̀, tabi nipa isọtẹlẹ, tabi nipa ẹkọ́? Bẹni pẹlu awọn nkan ti kò li ẹmí ti ndún, ibã ṣe fère tabi dùru, bikoṣepe ìyatọ ba wà ninu ohùn wọn, a ó ti ṣe mọ̀ ohun ti fère tabi ti dùru nwi? Nitoripe bi ohùn ipè kò ba daju, tani yio mura fun ogun? Bẹ̃ si li ẹnyin, bikoṣepe ẹnyin ba nfi ahọ́n nyin sọrọ ti o ye ni, a o ti ṣe mọ̀ ohun ti a nwi? nitoripe ẹnyin o sọ̀rọ si ofurufu. O le jẹ pe oniruru ohùn ni mbẹ li aiye, kò si si ọ̀kan ti kò ni itumọ. Njẹ bi emi kò mọ̀ itumọ ohùn na, emi o jasi alaigbede si ẹniti nsọ̀rọ, ẹniti nsọ̀rọ yio si jasi alaigbede si mi. Bẹ̃ si li ẹnyin, bi ẹnyin ti ni itara fun ẹ̀bun ẹmí, ẹ mã ṣe afẹri ati mã pọ si i fun idàgbàsoke ijọ. Nitorina jẹ ki ẹniti nsọ̀rọ li ède aimọ̀ gbadura ki o le mã ṣe itumọ̀. Nitori bi emi ba ngbadura li ède aimọ̀, ẹmí mi ngbadura, ṣugbọn oye mi jẹ alaileso. Njẹ kini rè? Emi o fi ẹmí gbadura, emi o si fi oye gbadura pẹlu: emi o fi ẹmí kọrin, emi o si fi oye kọrin pẹlu. Bi bẹ̃kọ, bi iwọ ba súre nipa, ẹmí, bawo ni ẹniti mbẹ ni ipò òpe yio ṣe ṣe Amin si idupẹ rẹ, nigbati kò mọ ohun ti iwọ wi? Nitori iwọ dupẹ gidigidi nitõtọ, ṣugbọn a kò fi ẹsẹ ẹnikeji rẹ mulẹ.

I. Kor 14:1-17 Yoruba Bible (YCE)

Ẹ máa lépa ìfẹ́. Ṣugbọn ẹ tún máa tiraka láti ní Ẹ̀mí Mímọ́, pàápàá jùlọ, ẹ̀bùn ìsọtẹ́lẹ̀. Nítorí ẹni tí ó bá ń fi èdè sọ̀rọ̀ kò bá eniyan sọ̀rọ̀, Ọlọrun ni ó ń bá sọ̀rọ̀. Nítorí pé kò sí ẹni tí ó gbọ́ ohun tí ó ń sọ. Ẹ̀mí ni ó gbé e tí ó fi ń sọ ohun àṣírí tí ó ń sọ tí kò yé eniyan. Ṣugbọn ẹni tí ó ń waasu ń bá eniyan sọ̀rọ̀ fún ìdàgbà ti ẹ̀mí, fún ìtùnú, ati ìwúrí. Ẹni tí ó ń fi èdè àjèjì sọ̀rọ̀, ara rẹ̀ nìkan ni ó ń mú dàgbà. Ṣugbọn ẹni tí ó ń waasu ń mú ìjọ dàgbà. Inú mi ìbá dún bí gbogbo yín bá lè máa fi èdè àjèjì sọ̀rọ̀. Ṣugbọn ohun tí ìbá dùn mọ́ mi ninu jùlọ ni pé kí ẹ lè máa waasu. Ẹni tí ó ń waasu ju ẹni tí ó ń fi èdè àjèjì sọ̀rọ̀ lọ, àfi bí ó bá túmọ̀ ohun tí ó fi èdè àjèjì sọ, kí ìjọ lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ fún ìdàgbà ẹ̀mí. Ará, ǹjẹ́ bí mo bá wá sọ́dọ̀ yín, tí mò ń fi èdè àjèjì sọ̀rọ̀, anfaani wo ni mo ṣe fun yín? Kò sí, àfi bí mo bá ṣe àlàyé nípa ìfihàn, tabi ìmọ̀, tabi iwaasu, tabi ẹ̀kọ́ tí mo fi èdè àjèjì sọ. Bí àwọn nǹkan tí kò ní ẹ̀mí tí à ń fi kọ orin, bíi fèrè tabi dùùrù, kò bá dún dáradára, ta ni yóo mọ ohùn orin tí wọn ń kọ? Bí ohun tí fèrè ogun bá ń wí kò bá yé eniyan, ta ni yóo palẹ̀ mọ́ fún ogun? Bẹ́ẹ̀ gan-an ni tí ẹ bá ń lo èdè àjèjì, tí ẹ kò lo ọ̀rọ̀ tí ó yé eniyan, báwo ni eniyan yóo ṣe mọ ohun tí ẹ ń sọ? Afẹ́fẹ́ lásán ni ẹ̀ ń sọ̀rọ̀ sí. Láìsí àní-àní, oríṣìíríṣìí èdè ni ó wà láyé, ṣugbọn kò sí èyí tí kò ní ìtumọ̀ ninu wọn. Nítorí náà, bí n kò bá gbọ́ èdè kan, mo di aláìgbédè lójú ẹni tí ó bá ń sọ èdè náà, òun náà sì di kògbédè lójú mi. Bẹ́ẹ̀ gan-an ni ó rí pẹlu yín. Níwọ̀n ìgbà tí ẹ̀ ń tiraka láti ní ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́, ẹ máa wá àwọn ẹ̀bùn tí yóo mú ìjọ dàgbà. Ìdí rẹ̀ nìyí tí ẹni tí ó ń fi èdè àjèjì sọ̀rọ̀ fi níláti gbadura fún ẹ̀bùn láti lè túmọ̀ rẹ̀. Bí mo bá ń fi èdè àjèjì gbadura, ẹ̀mí mi ni ó ń gbadura, ṣugbọn n kò lo òye ti inú ara mi nígbà náà. Kí ni kí á wá wí? N óo gbadura bí Ẹ̀mí bá ti darí mi, ṣugbọn n óo kọrin pẹlu òye. Bí o bá ń gbadura ọpẹ́ ní ọkàn rẹ, bí ẹnìkan bá wà níbẹ̀ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kọ́ nǹkan nípa igbagbọ, báwo ni yóo ṣe lè ṣe “Amin” sí adura ọpẹ́ tí ò ń gbà nígbà tí kò mọ ohun tí ò ń sọ? Ọpẹ́ tí ò ń ṣe lè dára ṣugbọn kò mú kí ẹlòmíràn lè dàgbà.

I. Kor 14:1-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ẹ máa lépa ìfẹ́, ki ẹ sí máa fi ìtara ṣàfẹ́rí ẹ̀bùn tí í ṣe ti Ẹ̀mí, ṣùgbọ́n ki ẹ kúkú lé máa sọtẹ́lẹ̀. Nítorí ẹni tí ń sọ̀rọ̀ ní èdè àìmọ̀, kò bá ènìyàn sọ̀rọ̀ bì ko ṣe Ọlọ́run: nítorí kó sí ẹni tí ó gbọ́; ṣùgbọ́n nípá ti Ẹ̀mí ó ń sọ ohun ìjìnlẹ̀; Ṣùgbọ́n ẹni tí ń sọtẹ́lẹ̀ ń ba àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ fún ìmúdúró, àti ìgbani-níyànjú, àti ìtùnú. Ẹni tí ń sọ̀rọ̀ ni èdè àìmọ̀ ń fi ẹsẹ̀ ara rẹ̀ mulẹ̀; ṣùgbọ́n ẹni ti ń sọtẹ́lẹ̀ ń fi ẹsẹ̀ ìjọ múlẹ̀. Ṣùgbọ́n ìbá wù mí ki gbogbo yín lè máa sọ onírúurú èdè, ṣùgbọ́n kí ẹ kúkú máa sọtẹ́lẹ̀: Ẹni tí ń sọtẹ́lẹ̀ pọ̀ jú ẹni ti ń fèdèfọ̀ lọ, bi kọ ṣe pé ó bá ń ṣe ìtumọ̀, kí ìjọ bá à lè kọ́ ẹ̀kọ́. Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ará, bí mo bá wá sí àárín yín, tí mo sì ń sọ̀rọ̀ ní èdè àìmọ̀, èrè kín ni èmi yóò jẹ́ fún yin, bi ko ṣe pé mo bá ń bá yín sọ̀rọ̀, yálà nípa ìṣípayá, tàbí ìmọ̀ tàbí nípá ìsọtẹ́lẹ̀, tàbí nípa ẹ̀kọ́? Bẹ́ẹ̀ ní pẹ̀lú àwọn nǹkan tí kò ní ẹ̀mí tí ń dún, ìbá à ṣe fèrè tàbí dùùrù bí kò ṣe pé ìyàtọ̀ bá wà nínú wọn, a ó tí ṣe mọ ohùn tí fèrè tàbí tí dùùrù ń wí? Nítorí pé bi ohùn ìpè kò bá dájú, ta ni yóò múra fún ogun? Bẹ́ẹ̀ sí ni ẹ̀yin, bí kò ṣe pé ẹ̀yin bá ń fi ahọ́n yín sọ̀rọ̀ tí ó yé ni, a ó ti ṣe mọ ohun ti ẹ ń wí? Nítorí pé ẹ̀yin yóò kàn máa sọ̀rọ̀ si afẹ́fẹ́ lásán. Ó lé jẹ́ pé onírúurú ohùn èdè ní ń bẹ ní ayé, kò sí ọ̀kan tí kò ní ìtumọ̀ Ǹjẹ́ bí èmí kò mọ ìtumọ̀ ohùn èdè náà, èmí ó jásí aláìgbédè sí ẹni tí ń sọ̀rọ̀, ẹni tí ń sọ̀rọ̀ yóò sí jásí aláìgbédè sí mi. Bẹ́ẹ̀ sì ní ẹ̀yin, bí ẹ̀yin ti ní ìtara fún ẹ̀bùn Ẹ̀mí, ẹ máa ṣe àfẹ́rí àti máa pọ̀ sí i fún ìdàgbàsókè ìjọ. Nítorí náà jẹ́ ki ẹni tí ń sọ̀rọ̀ ni èdè àìmọ̀ gbàdúrà ki ó lè máa ṣe ìtumọ̀ ohun tí ó sọ. Nítorí bí èmi bá ń gbàdúrà ní èdè àìmọ̀, ẹ̀mí mi ni ń gbàdúrà, ṣùgbọ́n ọkàn mi jẹ́ aláìléso. Ǹjẹ́ kín ni èmi yóò ṣe? Èmi yóò fi ẹ̀mí mi gbàdúrà, èmi yóò sí fi òye mi gbàdúrà pẹ̀lú; Èmi yóò fi ẹ̀mí mi kọrin, èmi yóò sí fi òye mi kọrin pẹ̀lú. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, bí ìwọ bá yin Ọlọ́run nípa ẹ̀mí, báwo ni ẹni tí ń bẹ ni ipò òpè yóò ṣe ṣe “Àmín” si ìdúpẹ́ rẹ, nígbà tí kò mọ ohun tí ìwọ wí? Nítorí ìwọ dúpẹ́ gidigidi nítòótọ́, ṣùgbọ́n a kó fi ẹsẹ̀ ẹnìkejì rẹ múlẹ̀.