I. Kor 13:8-13
I. Kor 13:8-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ifẹ kì iyẹ̀ lai: ṣugbọn biobaṣepe isọtẹlẹ ni, nwọn ó dopin; biobaṣepe ẹ̀bun ahọn ni, nwọn ó dakẹ; biobaṣepe ìmọ ni, yio di asan. Nitori awa mọ̀ li apakan, awa si nsọtẹlẹ li apakan. Ṣugbọn nigbati eyi ti o pé ba de, eyi ti iṣe ti apakan yio dopin. Nigbati mo wà li ewe, emi a mã sọ̀rọ bi èwe, emi a mã moye bi ewe, emi a mã gbero bi ewe: ṣugbọn nigbati mo di ọkunrin tan, mo fi ìwa ewe silẹ. Nitoripe nisisiyi awa nriran baibai ninu awojiji; ṣugbọn nigbana li ojukoju: nisisiyi mo mọ̀ li apakan; ṣugbọn nigbana li emi ó mọ̀ gẹgẹ bi mo si ti di mimọ̀ pẹlu. Njẹ nisisiyi igbagbọ́, ireti, ati ifẹ mbẹ, awọn mẹta yi: ṣugbọn eyiti o tobi jù ninu wọn ni ifẹ.
I. Kor 13:8-13 Yoruba Bible (YCE)
Ìfẹ́ kò lópin. Ní ti ọ̀rọ̀ wolii, wọn yóo di ohun tí kò wúlò mọ́. Ní ti àwọn èdè àjèjì wọn yóo di ohun tí a kò gbúròó mọ́. Ní ti ìmọ̀, yóo di ohun tí kò wúlò mọ́. Kò sí ẹni tí ó mọ ọ̀ràn ní àmọ̀tán, bẹ́ẹ̀ ni kò sí wolii tí ó ríran, ní àrítán. Ṣugbọn nígbà tí ohun tí ó pé bá dé, àwọn ohun tí kò pé yóo di ohun tí kò wúlò mọ́. Nígbà tí mo wà ní ọmọde, èmi a máa sọ̀rọ̀ bí ọmọde, èmi a máa gbèrò bí ọmọde, ṣugbọn nisinsinyii tí mo ti dàgbà, mo ti pa ìwà ọmọde tì. Nítorí nisinsinyii, à ń ríran bàìbàì ninu dígí. Ṣugbọn nígbà tí ó bá yá, ojú yóo kojú, a óo sì ríran kedere. Nisinsinyii, kò sí ohunkohun tí mo mọ̀ ní àmọ̀tán. Ṣugbọn nígbà náà, n óo ní ìmọ̀ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti mọ̀ mí. Ní gbolohun kan, àwọn nǹkan mẹta ni ó wà títí lae; igbagbọ, ìrètí, ati ìfẹ́; ṣugbọn èyí tí ó tóbi jù ninu wọn ni ìfẹ́.
I. Kor 13:8-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìfẹ́ kì í kùnà láé, kì í sì í yẹ̀ ṣùgbọ́n bí ó bá ṣe ìsọtẹ́lẹ̀ ni, wọn yóò dópin, bí ó bá ṣe ẹ̀bùn ahọ́n ni, wọn yóò dákẹ́, bí ó bá ṣe pé ìmọ̀ ni yóò di asán. Nítorí àwa mọ̀ ní apá kan, àwa sì sọtẹ́lẹ̀ ní apá kan. Ṣùgbọ́n nígbà tí èyí ti o pé bá dé, èyí tí í ṣe tí apá kan yóò dópin. Nígbà tí mó wà ni èwe, èmi á máa sọ̀rọ̀ bi èwe, èmi a máa mòye bí èwe, èmi a máa gbèrò bí èwe. Ṣùgbọ́n nígbà tí mó di ọkùnrin tán, mo fi ìwà èwe sílẹ̀. Nítorí pé nísinsin yìí àwa ń ríran bàìbàì nínú dígí; nígbà náà a ó rí í lójúkojú. Nísinsin yìí mò mọ̀ pé ní apá kan; nígbà náà èmi o mọ̀ lẹ́kùnrẹ́rẹ́, kódà bí mo ti dí mí mọ̀ pẹ̀lú. Ǹjẹ́ nísinsin yìí àwọn nǹkan mẹ́ta wọ̀nyí dúró: ìgbàgbọ́, ìrètí, àti ìfẹ́. Ṣùgbọ́n èyí tí o tóbi jù nínú wọn ni ìfẹ́.