I. Kor 13:4-8
I. Kor 13:4-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ifẹ a mã mu suru, a si mã ṣeun; ifẹ kì iṣe ilara; ifẹ kì isọrọ igberaga, kì ifẹ̀, Kì ihuwa aitọ́, kì iwá ohun ti ara rẹ̀, a kì imu u binu, bẹ̃ni kì igbiro ohun buburu; Kì iyọ̀ si aiṣododo, ṣugbọn a mã yọ̀ ninu otitọ; A mã farada ohun gbogbo, a mã gbà ohun gbogbo gbọ́, a mã reti ohun gbogbo, a mã fàiyarán ohun gbogbo. Ifẹ kì iyẹ̀ lai: ṣugbọn biobaṣepe isọtẹlẹ ni, nwọn ó dopin; biobaṣepe ẹ̀bun ahọn ni, nwọn ó dakẹ; biobaṣepe ìmọ ni, yio di asan.
I. Kor 13:4-8 Yoruba Bible (YCE)
Ìfẹ́ a máa mú sùúrù, a máa ṣe oore. Ìfẹ́ kì í jowú, kì í ṣe ìgbéraga, bẹ́ẹ̀ ni kì í fọ́nnu. Ìfẹ́ kì í ṣe ohun tí kò tọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì í hùwà ìmọ-tara-ẹni-nìkan. Kì í tètè bínú, bẹ́ẹ̀ ni kì í ka ẹ̀ṣẹ̀ sí eniyan lọ́rùn. Ìfẹ́ kì í fi nǹkan burúkú ṣe ayọ̀, ṣugbọn a máa yọ̀ ninu òtítọ́. Ìfẹ́ a máa fara da ohun gbogbo, a máa gba ohun gbogbo gbọ́, a máa ní ìrètí ninu ohun gbogbo, a sì máa foríti ohun gbogbo. Ìfẹ́ kò lópin. Ní ti ọ̀rọ̀ wolii, wọn yóo di ohun tí kò wúlò mọ́. Ní ti àwọn èdè àjèjì wọn yóo di ohun tí a kò gbúròó mọ́. Ní ti ìmọ̀, yóo di ohun tí kò wúlò mọ́.
I. Kor 13:4-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìfẹ́ a máa mú sùúrù, ìfẹ́ a máa ṣeun, ìfẹ́ kì í ṣe ìlara, ìfẹ́ kì í fẹ̀, ìfẹ́ kì í sọ̀rọ̀ ìgbéraga. Ìfẹ́ kì í hùwà àìtọ́, kì í wá ohun ara rẹ̀ nìkan. Ìfẹ́ kì í bínú fùfù, ìfẹ́ kì í fi búburú ọmọ ẹnìkejì sínú. Inú ìfẹ́ kì í dùn sí àìṣòótọ́. Ṣùgbọ́n inú rẹ̀ a máa dùn nígbà gbogbo. A máa faradà ohun gbogbo sí òtítọ́, a máa gba ohun gbogbo gbọ́, a máa retí ohun gbogbo, a máa fàyàrán ohun gbogbo. Ìfẹ́ kì í kùnà láé, kì í sì í yẹ̀ ṣùgbọ́n bí ó bá ṣe ìsọtẹ́lẹ̀ ni, wọn yóò dópin, bí ó bá ṣe ẹ̀bùn ahọ́n ni, wọn yóò dákẹ́, bí ó bá ṣe pé ìmọ̀ ni yóò di asán.