I. Kor 13:2-7
I. Kor 13:2-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bi mo si ni ẹbun isọtẹlẹ, ti mo si ni oye gbogbo ohun ijinlẹ, ati gbogbo ìmọ; bi mo si ni gbogbo igbagbọ́, tobẹ̃ ti mo le ṣí awọn òke nla nipò, ti emi kò si ni ifẹ, emi kò jẹ nkan. Bi mo si nfi gbogbo ohun ini mi bọ́ awọn talaka, bi mo si fi ara mi funni lati sun, ti emi kò si ni ifẹ, kò li ere kan fun mi. Ifẹ a mã mu suru, a si mã ṣeun; ifẹ kì iṣe ilara; ifẹ kì isọrọ igberaga, kì ifẹ̀, Kì ihuwa aitọ́, kì iwá ohun ti ara rẹ̀, a kì imu u binu, bẹ̃ni kì igbiro ohun buburu; Kì iyọ̀ si aiṣododo, ṣugbọn a mã yọ̀ ninu otitọ; A mã farada ohun gbogbo, a mã gbà ohun gbogbo gbọ́, a mã reti ohun gbogbo, a mã fàiyarán ohun gbogbo.
I. Kor 13:2-7 Yoruba Bible (YCE)
Ǹ báà ní ẹ̀bùn wolii, kí n ní gbogbo ìmọ̀, kí n mọ gbogbo àṣírí ayé, kí n ní igbagbọ tí ó gbóná tóbẹ́ẹ̀ tí ó lè ṣí òkè ní ìdí, tí n kò bá ní ìfẹ́, n kò já mọ́ nǹkankan. Ǹ báà kò gbogbo ohun tí mo ní, kí n fi tọrẹ, kódà kí n fi ara mi rú ẹbọ sísun, bí n kò bá ní ìfẹ́, kò ṣe anfaani kankan fún mi. Ìfẹ́ a máa mú sùúrù, a máa ṣe oore. Ìfẹ́ kì í jowú, kì í ṣe ìgbéraga, bẹ́ẹ̀ ni kì í fọ́nnu. Ìfẹ́ kì í ṣe ohun tí kò tọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì í hùwà ìmọ-tara-ẹni-nìkan. Kì í tètè bínú, bẹ́ẹ̀ ni kì í ka ẹ̀ṣẹ̀ sí eniyan lọ́rùn. Ìfẹ́ kì í fi nǹkan burúkú ṣe ayọ̀, ṣugbọn a máa yọ̀ ninu òtítọ́. Ìfẹ́ a máa fara da ohun gbogbo, a máa gba ohun gbogbo gbọ́, a máa ní ìrètí ninu ohun gbogbo, a sì máa foríti ohun gbogbo.
I. Kor 13:2-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bí mo bá ní ẹ̀bùn ìsọtẹ́lẹ̀, tí mo sì ní òye gbogbo ohun ìjìnlẹ̀, àti gbogbo ìmọ̀, bí mo sì ni gbogbo ìgbàgbọ́ tó bẹ́ẹ̀ tí mo lè ṣí àwọn òkè ńlá nídìí, tí èmi kò sì ní ìfẹ́, èmi kò jẹ nǹkan kan. Bí mo bá fi gbogbo nǹkan tí mo ní tọrẹ fún àwọn aláìní, tí mo sì fi ara mi fún ni láti sùn ṣùgbọ́n tí n kò ní ìfẹ́, kò ní èrè kan fún mi. Ìfẹ́ a máa mú sùúrù, ìfẹ́ a máa ṣeun, ìfẹ́ kì í ṣe ìlara, ìfẹ́ kì í fẹ̀, ìfẹ́ kì í sọ̀rọ̀ ìgbéraga. Ìfẹ́ kì í hùwà àìtọ́, kì í wá ohun ara rẹ̀ nìkan. Ìfẹ́ kì í bínú fùfù, ìfẹ́ kì í fi búburú ọmọ ẹnìkejì sínú. Inú ìfẹ́ kì í dùn sí àìṣòótọ́. Ṣùgbọ́n inú rẹ̀ a máa dùn nígbà gbogbo. A máa faradà ohun gbogbo sí òtítọ́, a máa gba ohun gbogbo gbọ́, a máa retí ohun gbogbo, a máa fàyàrán ohun gbogbo.