I. Kor 11:24-25
I. Kor 11:24-25 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati o si ti dupẹ, o bù u, o si wipe, Gbà, jẹ: eyi li ara mi ti a bu fun nyin: ẹ mã ṣe eyi ni iranti mi. Gẹgẹ bẹ̃ li o si mú ago, lẹhin onjẹ, o wipe, Ago yi ni majẹmu titun ninu ẹ̀jẹ mi: nigbakugba ti ẹnyin ba nmu u, ẹ mã ṣe eyi ni iranti mi.
I. Kor 11:24-25 Yoruba Bible (YCE)
lẹ́yìn tí ó ti dúpẹ́ tán, ó bù ú, ó ní, “Èyí ni ara mi tí ó wà fun yín. Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.” Bákan náà ni ó mú ife lẹ́yìn oúnjẹ, ó ní, “Èyí ni ife ti majẹmu titun tí a fi ẹ̀jẹ̀ mi dá. Nígbàkúùgbà tí ẹ bá ń mu ún, ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.”
I. Kor 11:24-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún àkàrà náà tan, ó bù ú, ó fi fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó sì wí pé, “Ẹ gbà kí ẹ sì jẹ, èyí ní ara mi tí a fi fún un yín. Ẹ máa ṣe eléyìí ni rántí mi.” Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ lẹ́yìn oúnjẹ alẹ́, ó sì mú ago wáìnì, ó sì wí pé, “Ago yìí ni májẹ̀mú tuntun nínú ẹ̀jẹ̀ mi, ẹ máa ṣe èyí, nígbàkígbà ti ẹ̀yìn bá ń mu ú, ní ìrántí mi.”