I. Kor 11:17-34

I. Kor 11:17-34 Bibeli Mimọ (YBCV)

Ṣugbọn niti aṣẹ ti mo nfun nyin yi, emi kò yìn nyin pe, ẹ npejọ kì iṣe fun rere, ṣugbọn fun buburu. Nitori lọna ikini, mo gbọ́ pe, nigbati ẹnyin pejọ ni ijọ, ìyapa mbẹ lãrin nyin; mo si gbà a gbọ́ li apakan. Nitoripe kò le ṣe ki o má si adamọ pẹlu larin nyin, ki awọn ti o daju larin nyin ba le farahàn. Nitorina nigbati ẹnyin ba pejọ si ibi kanna, kì iṣe lati jẹ Onjẹ Oluwa. Nitoripe nigbati ẹnyin ba njẹun, olukuluku nkọ́ jẹ onjẹ tirẹ̀, ebi a si mã pa ẹnikan, ọti a si mã pa ẹnikeji. Kinla? ẹnyin kò ni ile nibiti ẹ o mã jẹ, ti ẹ o si mã mu? tabi ẹnyin ngàn ijọ Ọlọrun, ẹnyin si ndojutì awọn ti kò ni? Kili emi o wi fun nyin? emi o ha yìn nyin ninu eyi? emi kò yìn nyin. Nitoripe lọwọ Oluwa li emi ti gbà eyiti mo si ti fifun nyin, pe Jesu Oluwa li oru ọjọ na ti a fi i han, o mu akara: Nigbati o si ti dupẹ, o bù u, o si wipe, Gbà, jẹ: eyi li ara mi ti a bu fun nyin: ẹ mã ṣe eyi ni iranti mi. Gẹgẹ bẹ̃ li o si mú ago, lẹhin onjẹ, o wipe, Ago yi ni majẹmu titun ninu ẹ̀jẹ mi: nigbakugba ti ẹnyin ba nmu u, ẹ mã ṣe eyi ni iranti mi. Nitori nigbakugba ti ẹnyin ba njẹ akara yi, ti ẹnyin ba si nmu ago yi, ẹnyin nkede ikú Oluwa titi yio fi de. Nitorina ẹnikẹni ti o ba jẹ akara, ti o si mu ago Oluwa laiyẹ, yio jẹbi ara ati ẹ̀jẹ Oluwa. Ṣugbọn ki enia ki o wadi ara rẹ̀ daju, bẹ̃ni ki o si jẹ ninu akara na, ki o si mu ninu ago na. Nitori ẹnikẹni ti o ba njẹ, ti o ba si nmu laimọ̀ ara Oluwa yatọ, o njẹ o si nmu ẹbi fun ara rẹ̀. Nitori idi eyi li ọ̀pọlọpọ ninu nyin ṣe di alailera ati olokunrun, ti ọ̀pọlọpọ si sùn. Ṣugbọn bi awa ba wadi ara wa, a kì yio da wa lẹjọ. Ṣugbọn nigbati a ba ndá wa lẹjọ, lati ọwọ́ Oluwa li a ti nnà wa, ki a má bã dá wa lẹbi pẹlu aiye. Nitorina, ẹnyin ará mi, nigbati ẹnyin ba pejọ lati jẹun, ẹ mã duro dè ara nyin. Bi ebi ba npa ẹnikẹni, ki o jẹun ni ile; ki ẹnyin ki o má bã pejọ fun ẹbi. Iyokù li emi ó si tò lẹsẹsẹ nigbati mo ba de.

I. Kor 11:17-34 Yoruba Bible (YCE)

Nígbà tí mò ń sọ èyí, nǹkankan wà tí n kò yìn yín fún, nítorí nígbà tí ẹ bá péjọ, ìpéjọpọ̀ yín ń ṣe ibi ju rere lọ. Nítorí, ní ọ̀nà kinni, mo gbọ́ pé nígbà tí ẹ bá péjọ pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìjọ, ìyapa a máa wà láàrin yín. Mo gbàgbọ́ pé òtítọ́ wà ninu ìròyìn yìí. Nítorí ìyapa níláti wà láàrin yín, kí àwọn tí ń ṣe ẹ̀tọ́ láàrin yín lè farahàn. Nítorí èyí, nígbà tí ẹ bá péjọ sí ibìkan náà, kì í ṣe Oúnjẹ Alẹ́ Oluwa ni ẹ̀ ń jẹ. Nítorí pé ẹnìkọ̀ọ̀kan ninu yín níí máa kánjú jẹun, ebi a máa pa àwọn kan nígbà tí àwọn mìíràn ti mu ọtí lámuyó! Ṣé ẹ kò ní ilé tí ẹ ti lè máa jẹ, kí ẹ máa mu ni? Àbí ẹ fẹ́ kó ẹ̀gàn bá ìjọ Ọlọrun ni? Ẹ fẹ́ dójú ti àwọn aláìní, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Kí ni kí n sọ fun yín? Ṣé kí n máa yìn yín ni? Rárá o! N kò ní yìn yín fún èyí. Nítorí láti ọ̀dọ̀ Oluwa ni mo ti gba ohun tí mo fi kọ yín, pé ní alẹ́ ọjọ́ tí a fi Jesu Oluwa lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́, ó mú burẹdi, lẹ́yìn tí ó ti dúpẹ́ tán, ó bù ú, ó ní, “Èyí ni ara mi tí ó wà fun yín. Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.” Bákan náà ni ó mú ife lẹ́yìn oúnjẹ, ó ní, “Èyí ni ife ti majẹmu titun tí a fi ẹ̀jẹ̀ mi dá. Nígbàkúùgbà tí ẹ bá ń mu ún, ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.” Nítorí nígbàkúùgbà tí ẹ bá ń jẹ burẹdi yìí, tí ẹ sì ń mu ninu ife yìí, ẹ̀ ń kéde ikú Oluwa títí yóo fi dé. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá ń jẹ burẹdi, tabi tí ó ń mu ninu ife Oluwa láìyẹ jẹ̀bi ìlòkulò ara ati ẹ̀jẹ̀ Oluwa. Kí olukuluku yẹ ara rẹ̀ wò kí ó tó jẹ ninu burẹdi, kí ó sì tó mu ninu ife Oluwa. Nítorí ẹni tí ó bá ń jẹ, tí ó ń mu láìmọ ìyàtọ̀ tí ó wà ninu ara Kristi, ìdájọ́ ni ó ń jẹ, tí ó sì ń mu, lórí ara rẹ̀. Nítorí èyí ni ọpọlọpọ ninu yín ṣe di aláìlera ati ọlọ́kùnrùn, tí ọpọlọpọ tilẹ̀ ti kú. Ṣugbọn tí a bá ti yẹ ara wa wò, a kò ní dá wa lẹ́jọ́. Ṣugbọn bí a bá bọ́ sinu ìdájọ́ Oluwa, ó fi ń bá wa wí ni, kí ó má baà dá wa lẹ́bi pẹlu àwọn yòókù. Nítorí náà, ẹ̀yin ará mi, nígbà tí ẹ bá péjọ láti jẹun, ẹ máa dúró de ara yín. Bí ebi bá ń pa ẹnikẹ́ni, kí ó jẹun kí ó tó kúrò ní ilé, kí ìpéjọpọ̀ yín má baà jẹ́ ìdálẹ́bi fun yín. Nígbà tí mo bá dé, n óo ṣe ètò nípa àwọn nǹkan tí ó kù.

I. Kor 11:17-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nínú àwọn àlàkalẹ̀ èmi ko ni yìn yín nítorí pé bí ẹ bá péjọ kì í ṣe fún rere bí ko ṣe fún búburú. Lọ́nà kìn-ín-ní, mo gbọ́ pe ìyapa máa ń wà láàrín yín ní ìgbà tí ẹ bá péjọpọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìjọ, mo sì gba èyí gbọ́ dé ààyè ibìkan. Kò sí àní àní, ìyàtọ̀ gbọdọ̀ wa láàrín yín, kí àwọn tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run láàrín yín le farahàn kedere. Nígbà tí ẹ bá pàdé láti jẹun, kì í ṣe oúnjẹ alẹ́ Olúwa ni ẹ máa ń jẹ. Ṣùgbọ́n tí ara yín, nígbà tí ẹ bá fẹ́ jẹun, olúkúlùkù yín a máa sáré jẹ oúnjẹ rẹ̀ láìdúró de ẹnìkejì rẹ̀. Ebi a sì máa pa wọ́n, ẹlòmíràn wọ́n sì ń mu àmuyó àti àmupara. Ṣé ẹ̀yin kò ní ilé tí ẹ ti lè jẹ, tí ẹ sì ti lè mu ni? Tàbí ẹ̀yin ń gan ìjọ Ọlọ́run ni? Ẹ̀yin sì ń dójútì àwọn aláìní? Kín ni kí èmi ó wí fún un yín? Èmi yóò ha yìn yín nítorí èyí? A! Rárá o. Èmi kọ́, n kò ní yìn yín. Nítorí èyí tí èmi gbà lọ́wọ́ Olúwa ni mo ti fi fún un yin. Ní alẹ́ ọjọ́ tí Judasi fihàn, Olúwa Jesu Kristi mú àkàrà. Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún àkàrà náà tan, ó bù ú, ó fi fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó sì wí pé, “Ẹ gbà kí ẹ sì jẹ, èyí ní ara mi tí a fi fún un yín. Ẹ máa ṣe eléyìí ni rántí mi.” Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ lẹ́yìn oúnjẹ alẹ́, ó sì mú ago wáìnì, ó sì wí pé, “Ago yìí ni májẹ̀mú tuntun nínú ẹ̀jẹ̀ mi, ẹ máa ṣe èyí, nígbàkígbà ti ẹ̀yìn bá ń mu ú, ní ìrántí mi.” Nítorí nígbàkúgbà tí ẹ bá ń jẹ lára àkàrà yìí, tí ẹ sì ǹ mu nínú ago yìí, ni ẹ tún sọ nípa ikú Olúwa. Ẹ máa ṣe eléyìí títí yóò fi padà dé. Nítorí náà tí ẹnikẹ́ni bá jẹ lára àkàrà yìí, tí ẹ sì ń mu nínú ago Olúwa yìí, ní ọ̀nà tí kò bójúmu, yóò jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ sí ara àti ẹ̀jẹ̀ Olúwa. Ìdí nìyìí tí ó fi yẹ kí ènìyàn yẹ ara rẹ̀ wò dáradára kí ó tó jẹ lára àkàrà nà án àti kí ó tó mu nínú ago náà. Nítorí tí ẹ bá jẹ lára àkàrà, tí ẹ sì mu nínú ago láìyẹ, tí ẹ kò ronú ara Kristi àti nǹkan tí ó túmọ̀ sí, ẹ̀ ń jẹ, ẹ sì ń mú ẹ̀bi ìdájọ́ Ọlọ́run wá sórí ara yín. Ìdí nìyìí tí ọ̀pọ̀ yín fi di ẹni tí kò lágbára mọ́, tí ọ̀pọ̀ yín sì ń ṣàìsàn, àwọn mìíràn nínú yín tilẹ̀ ti sùn. Ṣùgbọ́n tí ẹ bá yẹ ara yín wò dáradára, kí ẹ tó jẹ ẹ́, a kì yóò dá yín lẹ́jọ́. Ṣùgbọ́n nígbà tí a bá dá wa lẹ́jọ́, láti ọwọ́ Olúwa ni a ti nà wá, kí a má ba à dá wa lẹ́bi pẹ̀lú ayé. Nítorí náà, ẹ̀yin arákùnrin mi ọ̀wọ́n, nígbàkúgbà ti ẹ bá péjọ láti jẹ́ oúnjẹ alẹ́ Olúwa, tàbí fún ìsìn oúnjẹ alẹ́ Olúwa, ẹ dúró de ara yín. Bí ebi bá ń pa ẹnikẹ́ni nínú yin, kí ó jẹun láti ilé wá, kí ó má ba á mú ìjìyà wá sórí ara rẹ̀ nígbà tí ẹ bá péjọ. Tí mo bá dé, èmi yóò máa sọ̀rọ̀ lórí àwọn kókó-ọ̀rọ̀ ìyókù tí n kò ì ti fẹnu bà lẹ́sẹẹsẹ.