I. Kor 1:28-30
I. Kor 1:28-30 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ati awọn ohun aiye ti kò niyìn, ati awọn ohun ti a nkẹgàn, li Ọlọrun si ti yàn, ani, awọn ohun ti kò si, lati sọ awọn ohun ti o wà di asan: Ki o máṣe si ẹlẹran-ara ti yio ṣogo niwaju rẹ̀. Ṣugbọn nipasẹ rẹ̀ li ẹnyin wà ninu Kristi Jesu, ẹniti Ọlọrun fi ṣe ọgbọ́n, ati ododo, ati isọdimimọ́, ati idande fun wa
I. Kor 1:28-30 Yoruba Bible (YCE)
bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun yan àwọn ẹni tí kò níláárí ati àwọn ẹni tí kò já mọ́ nǹkankan rárá, àwọn tí ẹnikẹ́ni kò kà sí, láti rẹ àwọn tí ayé ń gbé gẹ̀gẹ̀ sílẹ̀. Ìdí tí Ọlọrun fi ṣe báyìí ni pé kí ẹnikẹ́ni má baà lè gbéraga níwájú òun. Nípa iṣẹ́ Ọlọrun, ẹ̀yin wà ní ìṣọ̀kan pẹlu Kristi Jesu. Òun ni Ọlọrun fi ṣe ọgbọ́n wa ati òdodo wa. Òun ni ó sọ wá di mímọ́, tí ó dá wa nídè.
I. Kor 1:28-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àti àwọn ohun tí ayé tí kò ní ìyìn, àti àwọn ohun tí a kẹ́gàn, ni Ọlọ́run sì ti yàn, àní àwọn ohun tí kò sí, láti sọ àwọn ohun tí ó wà di asán. Nítorí kí ó má ba à sí ẹnìkan tí yóò ṣògo níwájú rẹ̀. Nítorí rẹ̀ ni ẹ̀yin ṣe wà nínú Kristi Jesu ẹni ti ó jásí ọgbọ́n fún wa láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run—èyí ń ni, òdodo, ìwà mímọ́ àti ìràpadà wa.