I. Kor 1:25-26
I. Kor 1:25-26 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitoripe wère Ọlọrun gbọ́n jù enia lọ; ati ailera Ọlọrun li agbara jù enia lọ. Ẹ sa wo ìpè nyin, ará, bi o ti ṣepe kì iṣe ọ̀pọ awọn ọlọ́gbọn enia nipa ti ara, kì iṣe ọ̀pọ awọn alagbara, kì iṣe ọ̀pọ awọn ọlọlá li a pè
I. Kor 1:25-26 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí agọ̀ Ọlọrun gbọ́n ju eniyan lọ, àìlágbára Ọlọrun sì lágbára ju eniyan lọ! Ẹ̀yin ará, ẹ wo ọ̀nà tí Ọlọrun gbà pè yín. Kì í ṣe ọ̀pọ̀ ninu yín ni ọlọ́gbọ́n gẹ́gẹ́ bí èrò ẹ̀dá, ọ̀pọ̀ ninu yín kì í ṣe alágbára, ọ̀pọ̀ ninu yín kì í ṣe ọlọ́lá.
I. Kor 1:25-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí pé òmùgọ̀ Ọlọ́run jù ọgbọ́n ènìyàn lọ; àti aláìlera Ọlọ́run ni agbára jù ìlera ènìyàn lọ. Ará, ẹ kíyèsi ohun tí ẹ jẹ́ nígbà tí a pè yín. Kì í ṣe ọ̀pọ̀ yín jẹ ọlọ́gbọ́n nípa àgbékalẹ̀ ti ènìyàn, tàbí ọ̀pọ̀ nínú yín jẹ́ ènìyàn pàtàkì, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ọ̀pọ̀ nínú yín jẹ́ ọlọ́lá nípa ibi tí a gbé bí i.