I. Kor 1:18-31

I. Kor 1:18-31 Bibeli Mimọ (YBCV)

Nitoripe wère li ọ̀rọ agbelebu si awọn ti o nṣegbé; ṣugbọn si awa ti a ngbalà, agbara Ọlọrun ni. Nitoriti a kọ ọ pe, Emi ó pa ọgbọ́n awọn ọlọ́gbọn run, emi ó si sọ òye awọn olóye di asan. Ọlọ́gbọn na ha da? akọwe na ha da? ojiyan aiye yi na ha da? Ọlọrun kò ha ti sọ ọgbọ́n aiye yi di wère? Nitoripe ninu ọgbọ́n Ọlọrun niwọnbi aiye kò ti mọ̀ nitori ọgbọ́n, o wù Ọlọrun nipa wère iwasu lati gbà awọn ti o gbagbọ́ là. Nitoripe awọn Ju mbère àmi, awọn Hellene si nṣafẹri ọgbọ́n: Ṣugbọn awa nwasu Kristi ti a kàn mọ agbelebu, ikọsẹ̀ fun awọn Ju, ati wère fun awọn Hellene, Ṣugbọn fun awọn ti a pè, ati Ju ati Hellene, Kristi li agbara Ọlọrun, ati ọgbọ́n Ọlọrun. Nitoripe wère Ọlọrun gbọ́n jù enia lọ; ati ailera Ọlọrun li agbara jù enia lọ. Ẹ sa wo ìpè nyin, ará, bi o ti ṣepe kì iṣe ọ̀pọ awọn ọlọ́gbọn enia nipa ti ara, kì iṣe ọ̀pọ awọn alagbara, kì iṣe ọ̀pọ awọn ọlọlá li a pè: Ṣugbọn Ọlọrun ti yàn awọn ohun wère aiye lati fi dãmu awọn ọlọgbọ́n; Ọlọrun si ti yàn awọn ohun ailera aiye lati fi dãmu awọn ohun ti o li agbara; Ati awọn ohun aiye ti kò niyìn, ati awọn ohun ti a nkẹgàn, li Ọlọrun si ti yàn, ani, awọn ohun ti kò si, lati sọ awọn ohun ti o wà di asan: Ki o máṣe si ẹlẹran-ara ti yio ṣogo niwaju rẹ̀. Ṣugbọn nipasẹ rẹ̀ li ẹnyin wà ninu Kristi Jesu, ẹniti Ọlọrun fi ṣe ọgbọ́n, ati ododo, ati isọdimimọ́, ati idande fun wa: Pe, gẹgẹ bi a ti kọ ọ, Ẹniti o ba nṣogo, ki o mã ṣogo ninu Oluwa.

I. Kor 1:18-31 Yoruba Bible (YCE)

Nítorí ọ̀rọ̀ agbelebu Kristi jẹ́ ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ lójú àwọn tí ń ṣègbé. Ṣugbọn lójú àwọn tí à ń gbà là, agbára Ọlọrun ni. Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Ọlọrun wí pé, ‘Èmi óo pa ọgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n run, n óo pa ìmọ̀ àwọn amòye tì sápá kan.’ ” Ipò wo wá ni àwọn ọlọ́gbọ́n wà? Àwọn amòfin ńkọ́? Àwọn tí wọ́n mọ iyàn jà ní ayé yìí ńkọ́? Ṣebí Ọlọrun ti sọ ọgbọ́n ayé yìí di agọ̀! Bí ó ti jẹ́ ìfẹ́ Ọlọrun pé kì í ṣe ipasẹ̀ gbogbo ọgbọ́n ayé yìí ni eniyan yóo fi mọ Ọlọrun, ó wu Ọlọrun láti gba àwọn tí ó gbàgbọ́ là nípa iwaasu tí à ń wà, tí ó dàbí ọ̀rọ̀ òmùgọ̀. Nítorí àwọn Juu ń bèèrè àmì: àwọn Giriki ń lépa ọgbọ́n; ṣugbọn ní tiwa, àwa ń waasu Kristi tí wọ́n kàn mọ́ agbelebu. Ohun ìkọsẹ̀ ni iwaasu wa yìí jẹ́ lójú àwọn Juu, ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ sì ni lójú àwọn orílẹ̀-èdè yòókù; ṣugbọn lójú àwọn tí Ọlọrun pè, ìbáà ṣe Juu tabi Giriki, Kristi yìí ni agbára Ọlọrun, òun ni ọgbọ́n Ọlọrun. Nítorí agọ̀ Ọlọrun gbọ́n ju eniyan lọ, àìlágbára Ọlọrun sì lágbára ju eniyan lọ! Ẹ̀yin ará, ẹ wo ọ̀nà tí Ọlọrun gbà pè yín. Kì í ṣe ọ̀pọ̀ ninu yín ni ọlọ́gbọ́n gẹ́gẹ́ bí èrò ẹ̀dá, ọ̀pọ̀ ninu yín kì í ṣe alágbára, ọ̀pọ̀ ninu yín kì í ṣe ọlọ́lá. Ṣugbọn Ọlọrun ti yan àwọn nǹkan tí ayé kà sí agọ̀ láti fi dójú ti àwọn ọlọ́gbọ́n, ó yan àwọn nǹkan tí kò lágbára ti ayé, láti fi dójú ti àwọn alágbára; bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun yan àwọn ẹni tí kò níláárí ati àwọn ẹni tí kò já mọ́ nǹkankan rárá, àwọn tí ẹnikẹ́ni kò kà sí, láti rẹ àwọn tí ayé ń gbé gẹ̀gẹ̀ sílẹ̀. Ìdí tí Ọlọrun fi ṣe báyìí ni pé kí ẹnikẹ́ni má baà lè gbéraga níwájú òun. Nípa iṣẹ́ Ọlọrun, ẹ̀yin wà ní ìṣọ̀kan pẹlu Kristi Jesu. Òun ni Ọlọrun fi ṣe ọgbọ́n wa ati òdodo wa. Òun ni ó sọ wá di mímọ́, tí ó dá wa nídè. Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ pe: “Ẹni tí ó bá fẹ́ ṣe ìgbéraga, kí ó ṣe ìgbéraga nípa ohun tí Oluwa ṣe.”

I. Kor 1:18-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nítorí pé òmùgọ̀ ni ọ̀rọ̀ àgbélébùú jẹ́ sí àwọn tí ń ṣègbé, ṣùgbọ́n fún àwa tí a ń gbàlà ó jẹ́ agbára Ọlọ́run. Nítorí a tí kọ ọ́ pé: “Èmi yóò pa ọgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n run, òye àwọn olóye ni Èmi yóò sọ di asán.” Àwọn ọlọ́gbọ́n náà ha dá? Àwọn akọ̀wé náà ha dà? Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ayé yìí ha dà? Ọlọ́run kò ha ti sọ ọgbọ́n ayé yìí di aṣiwèrè? Nítorí pé, nínú ọgbọ́n Ọlọ́run, ayé kò le mọ̀ òun nípa ọgbọ́n àti ìṣeféfé wọn. Ó sì gba gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́ là nípa ìwàásù tí àwọn aráyé pè ní òmùgọ̀ àti ọ̀rọ̀ ọ yẹ̀yẹ́. Nítorí pé àwọn Júù ń béèrè ààmì, àwọn Helleni sí ń ṣàfẹ́rí ọgbọ́n, ṣùgbọ́n àwa ń wàásù Kristi ti a kàn mọ́ àgbélébùú, òkúta ìkọ̀sẹ̀ àwọn Júù àti òmùgọ̀ fún àwọn kèfèrí. Ṣùgbọ́n sí àwọn tí Ọlọ́run tí pè, àti àwọn Júù àti àwọn Giriki, Kristi ni agbára Ọlọ́run, àti ọgbọ́n Ọlọ́run. Nítorí pé òmùgọ̀ Ọlọ́run jù ọgbọ́n ènìyàn lọ; àti aláìlera Ọlọ́run ni agbára jù ìlera ènìyàn lọ. Ará, ẹ kíyèsi ohun tí ẹ jẹ́ nígbà tí a pè yín. Kì í ṣe ọ̀pọ̀ yín jẹ ọlọ́gbọ́n nípa àgbékalẹ̀ ti ènìyàn, tàbí ọ̀pọ̀ nínú yín jẹ́ ènìyàn pàtàkì, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ọ̀pọ̀ nínú yín jẹ́ ọlọ́lá nípa ibi tí a gbé bí i. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run tí yàn àwọn òmùgọ̀ ayé láti fi dààmú àwọn ọlọ́gbọ́n; Ọlọ́run sì ti yàn àwọn ohun aláìlera ayé láti fi dààmú àwọn ohun tí ó ni agbára. Àti àwọn ohun tí ayé tí kò ní ìyìn, àti àwọn ohun tí a kẹ́gàn, ni Ọlọ́run sì ti yàn, àní àwọn ohun tí kò sí, láti sọ àwọn ohun tí ó wà di asán. Nítorí kí ó má ba à sí ẹnìkan tí yóò ṣògo níwájú rẹ̀. Nítorí rẹ̀ ni ẹ̀yin ṣe wà nínú Kristi Jesu ẹni ti ó jásí ọgbọ́n fún wa láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run—èyí ń ni, òdodo, ìwà mímọ́ àti ìràpadà wa. Nítorí náà, bí a ti kọ ọ́ pé, “Ẹni ti ó bá ń ṣògo kí ó máa ṣògo nínú Olúwa.”

I. Kor 1:18-31

I. Kor 1:18-31 YBCV

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa