I. Kor 1:1-31

I. Kor 1:1-31 Bibeli Mimọ (YBCV)

PAULU, ẹniti a pè lati jẹ Aposteli Jesu Kristi nipa ifẹ Ọlọrun, ati Sostene arakunrin, Si ijọ enia Ọlọrun ti o wà ni Korinti, awọn ti a sọ di mimọ́ ninu Kristi Jesu, awọn ẹniti a npè li enia mimọ́, pẹlu gbogbo awọn ti npè orukọ Jesu Kristi Oluwa wa nibigbogbo, ẹniti iṣe tiwọn ati tiwa: Ore-ọfẹ si nyin, ati alafia, lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Oluwa wa Jesu Kristi. Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun mi nigbagbogbo nitori nyin, nitori ore-ọfẹ Ọlọrun ti a fifun nyin ninu Jesu Kristi; Nitoripe nipasẹ rẹ̀ li a ti sọ nyin di ọlọrọ̀ li ohun gbogbo, ninu ọ̀rọ-isọ gbogbo, ati ninu ìmọ gbogbo; Ani gẹgẹ bi a ti fi idi ẹrí Kristi kalẹ ninu nyin: Tobẹ ti ẹnyin kò fi rẹ̀hin ninu ẹ̀bunkẹbun; ti ẹ si nreti ifarahàn Oluwa wa Jesu Kristi: Ẹniti yio si fi idi nyin kalẹ titi de opin, ki ẹnyin ki o le jẹ alailẹgàn li ọjọ Oluwa wa Jesu Kristi. Olododo li Ọlọrun, nipasẹ ẹniti a pè nyin sinu ìdapọ Ọmọ rẹ̀ Jesu Kristi Oluwa wa. Mo si bẹ̀ nyin, ará, li orukọ Oluwa wa Jesu Kristi, ki gbogbo nyin mã sọ̀rọ ohun kanna, ati ki ìyapa ki o máṣe si ninu nyin; ṣugbọn ki a le ṣe nyin pé ni inu kanna, ati ni ìmọ kanna. Nitori a ti fihàn mi nipa tinyin, ará mi, lati ọdọ awọn ara ile Kloe, pe ìja mbẹ larin nyin. Njẹ eyi ni mo wipe, olukuluku nyin nwipe, Emi ni ti Paulu; ati emi ni ti Apollo; ati emi ni ti Kefa; ati emi ni ti Kristi. A ha pin Kristi bi? iṣe Paulu li a kàn mọ agbelebu fun nyin bi? tabi li orukọ Paulu li a baptisi nyin si? Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun pe emi kò baptisi ẹnikẹni ninu nyin, bikoṣe Krispu ati Gaiu; Ki ẹnikẹni ki o máṣe wipe mo ti mbaptisi li orukọ emi tikarami. Mo si baptisi awọn ara ile Stefana pẹlu: lẹhin eyi emi kò mọ̀ bi mo ba baptisi ẹlomiran pẹlu. Nitori Kristi kò rán mi lọ ibaptisi, bikoṣe lati wãsu ihinrere: kì iṣe nipa ọgbọ́n ọ̀rọ, ki a máṣe sọ agbelebu Kristi di alailagbara. Nitoripe wère li ọ̀rọ agbelebu si awọn ti o nṣegbé; ṣugbọn si awa ti a ngbalà, agbara Ọlọrun ni. Nitoriti a kọ ọ pe, Emi ó pa ọgbọ́n awọn ọlọ́gbọn run, emi ó si sọ òye awọn olóye di asan. Ọlọ́gbọn na ha da? akọwe na ha da? ojiyan aiye yi na ha da? Ọlọrun kò ha ti sọ ọgbọ́n aiye yi di wère? Nitoripe ninu ọgbọ́n Ọlọrun niwọnbi aiye kò ti mọ̀ nitori ọgbọ́n, o wù Ọlọrun nipa wère iwasu lati gbà awọn ti o gbagbọ́ là. Nitoripe awọn Ju mbère àmi, awọn Hellene si nṣafẹri ọgbọ́n: Ṣugbọn awa nwasu Kristi ti a kàn mọ agbelebu, ikọsẹ̀ fun awọn Ju, ati wère fun awọn Hellene, Ṣugbọn fun awọn ti a pè, ati Ju ati Hellene, Kristi li agbara Ọlọrun, ati ọgbọ́n Ọlọrun. Nitoripe wère Ọlọrun gbọ́n jù enia lọ; ati ailera Ọlọrun li agbara jù enia lọ. Ẹ sa wo ìpè nyin, ará, bi o ti ṣepe kì iṣe ọ̀pọ awọn ọlọ́gbọn enia nipa ti ara, kì iṣe ọ̀pọ awọn alagbara, kì iṣe ọ̀pọ awọn ọlọlá li a pè: Ṣugbọn Ọlọrun ti yàn awọn ohun wère aiye lati fi dãmu awọn ọlọgbọ́n; Ọlọrun si ti yàn awọn ohun ailera aiye lati fi dãmu awọn ohun ti o li agbara; Ati awọn ohun aiye ti kò niyìn, ati awọn ohun ti a nkẹgàn, li Ọlọrun si ti yàn, ani, awọn ohun ti kò si, lati sọ awọn ohun ti o wà di asan: Ki o máṣe si ẹlẹran-ara ti yio ṣogo niwaju rẹ̀. Ṣugbọn nipasẹ rẹ̀ li ẹnyin wà ninu Kristi Jesu, ẹniti Ọlọrun fi ṣe ọgbọ́n, ati ododo, ati isọdimimọ́, ati idande fun wa: Pe, gẹgẹ bi a ti kọ ọ, Ẹniti o ba nṣogo, ki o mã ṣogo ninu Oluwa.

I. Kor 1:1-31 Yoruba Bible (YCE)

Èmi Paulu, tí Ọlọrun pè láti jẹ́ òjíṣẹ́ Kristi Jesu, ati Sositene arakunrin wa ni à ń kọ ìwé yìí– Sí ìjọ Ọlọrun ti ó wà ní Kọrinti, àwọn tí a yà sí mímọ́ nípa ìṣọ̀kan pẹlu Kristi Jesu, tí a pè láti jẹ́ eniyan ọ̀tọ̀, ati gbogbo àwọn tí ń pe orúkọ Oluwa wa Jesu Kristi níbi gbogbo, Jesu tíí ṣe Oluwa tiwọn ati tiwa. Kí oore-ọ̀fẹ́ ati alaafia láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Baba wa ati Oluwa Jesu Kristi kí ó máa wà pẹlu yín. Mò ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun mi nígbà gbogbo nítorí yín, nítorí oore-ọ̀fẹ́ tí Ọlọrun fun yín ninu Kristi Jesu. Nítorí pé ẹ ní ọpọlọpọ ẹ̀bùn ninu Kristi: ẹ ní ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ sísọ, ẹ sì tún ní ẹ̀bùn ìmọ̀. Ẹ̀rí Kristi ti fẹsẹ̀ múlẹ̀ láàrin yín, tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé kò sí ẹ̀bùn Ẹ̀mí kan tí ó kù tí ẹ kò ní. Ẹ wá ń fi ìtara retí ìfarahàn Oluwa wa Jesu Kristi, ẹni tí yóo fi ẹsẹ̀ yín múlẹ̀ títí dé òpin, tí ẹ óo fi wà láì lẹ́gàn ní ọjọ́ ìfarahàn Oluwa wa, Jesu Kristi. Ẹni tí ó tó gbẹ́kẹ̀lé ni Ọlọrun tí ó pè yín sinu ìṣọ̀kan pẹlu ọmọ rẹ̀ Jesu Kristi, Oluwa wa. Ẹ̀yin ará, mo fi orúkọ Oluwa wa Jesu Kristi bẹ̀ yín, gbogbo yín, ẹ fohùn ṣọ̀kan, kí ó má sí ìyapa láàrin yín. Ẹ jẹ́ kí ọkàn yín ṣe ọ̀kan, kí èrò yín sì papọ̀. Nítorí pé ninu ìròyìn tí àwọn ará Kiloe mú wá, ó hàn sí mi gbangba pé ìjà wà láàrin yín. Ohun tí mò ń wí ni pé olukuluku yín ní ń sọ tirẹ̀. Bí ẹnìkan ti ń wí pé. “Ẹ̀yìn Paulu ni èmi wà,” ni ẹlòmíràn ń wí pé. “Ẹ̀yìn Apolo ni èmi wà,” tí ẹlòmíràn tún ń wí pé, “Ẹ̀yìn Peteru ni mo wà ní tèmi.” Ẹlòmíràn sì ń wí pé, “Ẹ̀yìn Kristi ni èmi wà.” Ṣé Kristi náà ni ó wá pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ báyìí? Ṣé èmi Paulu ni wọ́n kàn mọ́ agbelebu fun yín? Àbí ní orúkọ Paulu ni wọ́n ṣe ìrìbọmi fun yín? Mo dúpẹ́ pé n kò ṣe ìrìbọmi fún ẹnikẹ́ni ninu yín, àfi Kirisipu ati Gaiyu. Kí ẹnikẹ́ni má baà wí pé orúkọ mi ni wọ́n fi ṣe ìrìbọmi fún òun. Mo tún ranti! Mo ṣe ìrìbọmi fún ìdílé Stefana. N kò tún ranti ẹlòmíràn tí mo ṣe ìrìbọmi fún mọ́. Nítorí pé Kristi kò fi iṣẹ́ ṣíṣe ìrìbọmi rán mi, iṣẹ́ iwaasu ìyìn rere ni ó fi rán mi, kì í sìí ṣe nípa ọ̀rọ̀ ọgbọ́n, kí agbelebu Kristi má baà di òfo. Nítorí ọ̀rọ̀ agbelebu Kristi jẹ́ ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ lójú àwọn tí ń ṣègbé. Ṣugbọn lójú àwọn tí à ń gbà là, agbára Ọlọrun ni. Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Ọlọrun wí pé, ‘Èmi óo pa ọgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n run, n óo pa ìmọ̀ àwọn amòye tì sápá kan.’ ” Ipò wo wá ni àwọn ọlọ́gbọ́n wà? Àwọn amòfin ńkọ́? Àwọn tí wọ́n mọ iyàn jà ní ayé yìí ńkọ́? Ṣebí Ọlọrun ti sọ ọgbọ́n ayé yìí di agọ̀! Bí ó ti jẹ́ ìfẹ́ Ọlọrun pé kì í ṣe ipasẹ̀ gbogbo ọgbọ́n ayé yìí ni eniyan yóo fi mọ Ọlọrun, ó wu Ọlọrun láti gba àwọn tí ó gbàgbọ́ là nípa iwaasu tí à ń wà, tí ó dàbí ọ̀rọ̀ òmùgọ̀. Nítorí àwọn Juu ń bèèrè àmì: àwọn Giriki ń lépa ọgbọ́n; ṣugbọn ní tiwa, àwa ń waasu Kristi tí wọ́n kàn mọ́ agbelebu. Ohun ìkọsẹ̀ ni iwaasu wa yìí jẹ́ lójú àwọn Juu, ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ sì ni lójú àwọn orílẹ̀-èdè yòókù; ṣugbọn lójú àwọn tí Ọlọrun pè, ìbáà ṣe Juu tabi Giriki, Kristi yìí ni agbára Ọlọrun, òun ni ọgbọ́n Ọlọrun. Nítorí agọ̀ Ọlọrun gbọ́n ju eniyan lọ, àìlágbára Ọlọrun sì lágbára ju eniyan lọ! Ẹ̀yin ará, ẹ wo ọ̀nà tí Ọlọrun gbà pè yín. Kì í ṣe ọ̀pọ̀ ninu yín ni ọlọ́gbọ́n gẹ́gẹ́ bí èrò ẹ̀dá, ọ̀pọ̀ ninu yín kì í ṣe alágbára, ọ̀pọ̀ ninu yín kì í ṣe ọlọ́lá. Ṣugbọn Ọlọrun ti yan àwọn nǹkan tí ayé kà sí agọ̀ láti fi dójú ti àwọn ọlọ́gbọ́n, ó yan àwọn nǹkan tí kò lágbára ti ayé, láti fi dójú ti àwọn alágbára; bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun yan àwọn ẹni tí kò níláárí ati àwọn ẹni tí kò já mọ́ nǹkankan rárá, àwọn tí ẹnikẹ́ni kò kà sí, láti rẹ àwọn tí ayé ń gbé gẹ̀gẹ̀ sílẹ̀. Ìdí tí Ọlọrun fi ṣe báyìí ni pé kí ẹnikẹ́ni má baà lè gbéraga níwájú òun. Nípa iṣẹ́ Ọlọrun, ẹ̀yin wà ní ìṣọ̀kan pẹlu Kristi Jesu. Òun ni Ọlọrun fi ṣe ọgbọ́n wa ati òdodo wa. Òun ni ó sọ wá di mímọ́, tí ó dá wa nídè. Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ pe: “Ẹni tí ó bá fẹ́ ṣe ìgbéraga, kí ó ṣe ìgbéraga nípa ohun tí Oluwa ṣe.”

I. Kor 1:1-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Paulu, ẹni ti a pé láti jẹ́ aposteli Kristi Jesu nípa ìfẹ́ Ọlọ́run àti Sostene arákùnrin wa. Sí ìjọ ènìyàn Ọlọ́run ni Kọrinti, sí àwọn ti a sọ di mímọ́ nínú Kristi Jesu àti àwọn ti a pè láti jẹ́ mímọ́ pẹ̀lú gbogbo ènìyàn ni ibikíbi ti ń pe orúkọ Olúwa wa Jesu Kristi ẹni ti ń ṣe Olúwa tiwọn àti ti àwa náà. Oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà fún yín láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa àti Olúwa wa tí í ṣe Jesu Kristi. Nígbà gbogbo ni mo ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ tó fi fún un yín nínú Kristi Jesu. Nítorí nínú rẹ̀ ni a ti sọ yín di ọlọ́rọ̀ nínú ọ̀rọ̀ sísọ yín gbogbo àti nínú ìmọ̀ yín gbogbo. Nítorí ẹ̀rí wa nínú Kristi ni a ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ nínú yín. Nítorí náà ẹ̀yin kò ṣe aláìní nínú èyíkéyìí ẹ̀bùn ẹ̀mí, bí ẹ̀yin ṣe ń retí ìfarahàn Olúwa wa Jesu Kristi. Òun yóò sì mú yín dúró títí dé òpin, kí ẹ̀yin kí ó lè jẹ́ aláìlábùkù ní ọjọ́ Olúwa wa Jesu Kristi. Ọlọ́run, nípasẹ̀ ẹni ti a pè yín sínú ìdàpọ̀ pẹ̀lú Ọmọ rẹ̀ Jesu Kristi Olúwa wa, jẹ́ Olóòtítọ́. Mo bẹ̀ yín ẹ̀yin ara, ní orúkọ Olúwa wa Jesu Kristi, pé kí gbogbo yín fohùn ṣọ̀kan kí ó máa ṣe sí ìyapa láàrín yín, àti pé kí a lè ṣe yín pé ní inú àti ìmọ̀ kan náà. Ẹ̀yin ará mi, àwọn kan láti ilé Kloe sọ di mí mọ̀ fún mi pé ìjà ń bẹ́ láàrín yín. Ohun tí mo ń sọ ní pé: Olúkúlùkù yín ń wí pé, “Èmí tẹ̀lé Paulu”; “Èmi tẹ̀lé Apollo” òmíràn wí pé “Èmi tẹ̀lé Kefa, Peteru”; àti ẹlòmíràn wí pé “Èmi tẹ̀lé Kristi.” Ǹjẹ́ a ha pín Kristi bí? Ṣé a kan Paulu mọ́ àgbélébùú fún un yín bí? Ǹjẹ́ a tẹ̀ yín bọ omi ní orúkọ Paulu bí? Inú mi dún púpọ̀ pé èmi kò tẹ ẹnikẹ́ni nínú yín bọ omi yàtọ̀ sí Krisipu àti Gaiu. Nítorí náà kò sí ẹni tí ó lè sọ pé òun ṣe ìtẹ̀bọmi ní orúkọ èmi fúnra ara mi. (Bẹ́ẹ̀ ni, mo tún tẹ ìdílé Stefana bọ omi; lẹ́yìn èyí, èmí kò rántí pé mo tẹ ẹnikẹ́ni bọ omi mọ́ níbikíbi). Nítorí Kristi kò rán mi láti máa ṣe ìtẹ̀bọmi, ṣùgbọ́n ó rán mi láti máa wàásù ìhìnrere: kì í ṣe nípa ọgbọ́n ènìyàn, kí a máa ṣe sọ àgbélébùú Kristi dí aláìlágbára. Nítorí pé òmùgọ̀ ni ọ̀rọ̀ àgbélébùú jẹ́ sí àwọn tí ń ṣègbé, ṣùgbọ́n fún àwa tí a ń gbàlà ó jẹ́ agbára Ọlọ́run. Nítorí a tí kọ ọ́ pé: “Èmi yóò pa ọgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n run, òye àwọn olóye ni Èmi yóò sọ di asán.” Àwọn ọlọ́gbọ́n náà ha dá? Àwọn akọ̀wé náà ha dà? Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ayé yìí ha dà? Ọlọ́run kò ha ti sọ ọgbọ́n ayé yìí di aṣiwèrè? Nítorí pé, nínú ọgbọ́n Ọlọ́run, ayé kò le mọ̀ òun nípa ọgbọ́n àti ìṣeféfé wọn. Ó sì gba gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́ là nípa ìwàásù tí àwọn aráyé pè ní òmùgọ̀ àti ọ̀rọ̀ ọ yẹ̀yẹ́. Nítorí pé àwọn Júù ń béèrè ààmì, àwọn Helleni sí ń ṣàfẹ́rí ọgbọ́n, ṣùgbọ́n àwa ń wàásù Kristi ti a kàn mọ́ àgbélébùú, òkúta ìkọ̀sẹ̀ àwọn Júù àti òmùgọ̀ fún àwọn kèfèrí. Ṣùgbọ́n sí àwọn tí Ọlọ́run tí pè, àti àwọn Júù àti àwọn Giriki, Kristi ni agbára Ọlọ́run, àti ọgbọ́n Ọlọ́run. Nítorí pé òmùgọ̀ Ọlọ́run jù ọgbọ́n ènìyàn lọ; àti aláìlera Ọlọ́run ni agbára jù ìlera ènìyàn lọ. Ará, ẹ kíyèsi ohun tí ẹ jẹ́ nígbà tí a pè yín. Kì í ṣe ọ̀pọ̀ yín jẹ ọlọ́gbọ́n nípa àgbékalẹ̀ ti ènìyàn, tàbí ọ̀pọ̀ nínú yín jẹ́ ènìyàn pàtàkì, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ọ̀pọ̀ nínú yín jẹ́ ọlọ́lá nípa ibi tí a gbé bí i. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run tí yàn àwọn òmùgọ̀ ayé láti fi dààmú àwọn ọlọ́gbọ́n; Ọlọ́run sì ti yàn àwọn ohun aláìlera ayé láti fi dààmú àwọn ohun tí ó ni agbára. Àti àwọn ohun tí ayé tí kò ní ìyìn, àti àwọn ohun tí a kẹ́gàn, ni Ọlọ́run sì ti yàn, àní àwọn ohun tí kò sí, láti sọ àwọn ohun tí ó wà di asán. Nítorí kí ó má ba à sí ẹnìkan tí yóò ṣògo níwájú rẹ̀. Nítorí rẹ̀ ni ẹ̀yin ṣe wà nínú Kristi Jesu ẹni ti ó jásí ọgbọ́n fún wa láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run—èyí ń ni, òdodo, ìwà mímọ́ àti ìràpadà wa. Nítorí náà, bí a ti kọ ọ́ pé, “Ẹni ti ó bá ń ṣògo kí ó máa ṣògo nínú Olúwa.”

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa