I. Kor 1:1-3
I. Kor 1:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Paulu, ẹni ti a pé láti jẹ́ aposteli Kristi Jesu nípa ìfẹ́ Ọlọ́run àti Sostene arákùnrin wa. Sí ìjọ ènìyàn Ọlọ́run ni Kọrinti, sí àwọn ti a sọ di mímọ́ nínú Kristi Jesu àti àwọn ti a pè láti jẹ́ mímọ́ pẹ̀lú gbogbo ènìyàn ni ibikíbi ti ń pe orúkọ Olúwa wa Jesu Kristi ẹni ti ń ṣe Olúwa tiwọn àti ti àwa náà. Oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà fún yín láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa àti Olúwa wa tí í ṣe Jesu Kristi.
I. Kor 1:1-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
PAULU, ẹniti a pè lati jẹ Aposteli Jesu Kristi nipa ifẹ Ọlọrun, ati Sostene arakunrin, Si ijọ enia Ọlọrun ti o wà ni Korinti, awọn ti a sọ di mimọ́ ninu Kristi Jesu, awọn ẹniti a npè li enia mimọ́, pẹlu gbogbo awọn ti npè orukọ Jesu Kristi Oluwa wa nibigbogbo, ẹniti iṣe tiwọn ati tiwa: Ore-ọfẹ si nyin, ati alafia, lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Oluwa wa Jesu Kristi.

I. Kor 1:1-3 Yoruba Bible (YCE)
Èmi Paulu, tí Ọlọrun pè láti jẹ́ òjíṣẹ́ Kristi Jesu, ati Sositene arakunrin wa ni à ń kọ ìwé yìí– Sí ìjọ Ọlọrun ti ó wà ní Kọrinti, àwọn tí a yà sí mímọ́ nípa ìṣọ̀kan pẹlu Kristi Jesu, tí a pè láti jẹ́ eniyan ọ̀tọ̀, ati gbogbo àwọn tí ń pe orúkọ Oluwa wa Jesu Kristi níbi gbogbo, Jesu tíí ṣe Oluwa tiwọn ati tiwa. Kí oore-ọ̀fẹ́ ati alaafia láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Baba wa ati Oluwa Jesu Kristi kí ó máa wà pẹlu yín.