I. Kro 4:9-10
I. Kro 4:9-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
Jabesi si ṣe ọlọla jù awọn arakunrin rẹ̀ lọ: iya rẹ̀ si pe orukọ rẹ̀ ni Jabesi, wipe, Nitoriti mo bi i pẹlu ibanujẹ. Jabesi si ké pè Ọlọrun Israeli, wipe, Iwọ iba jẹ bukún mi nitõtọ, ki o si sọ àgbegbe mi di nla, ki ọwọ rẹ ki o si wà pẹlu mi, ati ki iwọ ki o má si jẹ ki emi ri ibi, ki emi má si ri ibinujẹ! Ọlọrun si mu ohun ti o tọrọ ṣẹ.
I. Kro 4:9-10 Yoruba Bible (YCE)
Ọkunrin kan, tí à ń pè ní Jabesi, jẹ́ eniyan pataki ju àwọn arakunrin rẹ̀ lọ. Ìyá rẹ̀ sọ ọ́ ní orúkọ yìí nítorí ìrora pupọ tí ó ní nígbà tí ó bí i. Jabesi gbadura sí Ọlọrun Israẹli pé, “Ọlọrun jọ̀wọ́ bukun mi, sì jẹ́ kí ilẹ̀ ìní mi pọ̀ sí i. Wà pẹlu mi, pa mí mọ́ kúrò ninu ewu, má jẹ́ kí jamba ṣe mí!” Ọlọrun sì ṣe ohun tí ó fẹ́ fún un.
I. Kro 4:9-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Jabesi sì ní ọlá ju àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin lọ. Ìyá rẹ̀ sì sọ ọ́ ní Jabesi wí pé, “Mo bí i nínú ìpọ́njú.” Jabesi sì kígbe sókè sí Ọlọ́run Israẹli wí pé, “Háà, Ìwọ yóò bùkún fún, ìwọ yóò sì mú agbègbè mi tóbi! Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ kí ó wà pẹ̀lú mi kí o sì pa mi mọ́ kúrò nínú ibi; kí èmi kí ó le ní ìdáǹdè kúrò nínú ìrora.” Ọlọ́run sì gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ rẹ̀.