I. Kro 3:1-10
I. Kro 3:1-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
WỌNYI li awọn ọmọ Dafidi, ti a bi fun u ni Hebroni; akọbi Amnoni, lati ọdọ Ahinoamu ara Jesreeli; ekeji Danieli, lati ọdọ Abigaili ara Karmeli; Ẹkẹta, Absalomu ọmọ Maaka ọmọbinrin Talmai ọba Gesuri; ẹkẹrin, Adonijah ọmọ Haggiti. Ẹkarun, Ṣefatiah lati ọdọ Abitali; ẹkẹfa Itreamu lati ọdọ Ẹgla aya rẹ̀. Awọn mẹfa wọnyi li a bi fun u ni Hebroni; nibẹ li o si jọba li ọdun meje on oṣù mẹfa: ati ni Jerusalemu li o jọba li ọdun mẹtalelọgbọn. Wọnyi li a si bi fun u ni Jerusalemu; Ṣimea, ati Ṣobabu, ati Natani, ati Solomoni, mẹrin, lati ọdọ Batṣua ọmọbinrin Ammieli: Abhari pẹlu, ati Eliṣama, ati Elifeleti, Ati Noga, ati Nefegi, ati Jafia, Ati Eliṣama, ati Eliada, ati Elifeleti mẹsan. Wọnyi ni gbogbo awọn ọmọ Dafidi, laika awọn ọmọ àle rẹ̀, ati Tamari arabinrin wọn. Ọmọ Solomoni si ni Rehoboamu, Abia ọmọ rẹ̀, Asa ọmọ rẹ̀, Jehoṣafati ọmọ rẹ̀.
I. Kro 3:1-10 Yoruba Bible (YCE)
Àwọn ọmọ Dafidi tí a bí fún un ní Heburoni nìwọ̀nyí, bí wọ́n ṣe tẹ̀lé ara wọn: Aminoni tí Ahinoamu ará Jesireeli bí fún un ni àkọ́bí rẹ̀, lẹ́yìn rẹ̀ ni Daniẹli, ọmọ Abigaili ará Kamẹli. Ẹkẹta ni Absalomu, ọmọ Maaka, ọmọbinrin Talimai, ọba ìlú Geṣuri; lẹ́yìn náà Adonija ọmọ Hagiti. Ẹkarun-un ni Ṣefataya, ọmọ Abitali; lẹ́yìn rẹ̀ ni Itireamu ọmọ Egila. Ní Heburoni, níbi tí Dafidi ti jọba fún ọdún meje ati ààbọ̀, ni wọ́n ti bí àwọn mẹfẹẹfa fún un. Lẹ́yìn náà, Dafidi jọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹtalelọgbọn. Àwọn ọmọ tí Dafidi bí ní Jerusalẹmu nìwọ̀nyí: Batiṣeba, ọmọbinrin Amieli, bí ọmọ mẹrin fún un: Ṣimea, Ṣobabu, Natani ati Solomoni. Àwọn ọmọ mẹsan-an mìíràn tí Dafidi tún bí ni: Ibihari, Eliṣua, ati Elipeleti; Noga, Nefegi, ati Jafia, Eliṣama, Eliada, ati Elifeleti, Dafidi ni ó bí gbogbo wọn, yàtọ̀ sí àwọn ọmọ tí àwọn obinrin mìíràn tún bí fún un. Ó bí ọmọbinrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Tamari. Àwọn ọmọ Solomoni ọba nìwọ̀nyí: Rehoboamu, Abija, Asa, ati Jehoṣafati
I. Kro 3:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àwọn wọ̀nyí sì ni ọmọ Dafidi tí a bí fún un ní Hebroni: Àkọ́bí sì ni Amnoni ọmọ Ahinoamu ti Jesreeli; èkejì sì ni Daniẹli ọmọ Abigaili ará Karmeli; Ẹ̀kẹta sì ni Absalomu ọmọ Maaka ọmọbìnrin Talmai ọba Geṣuri bí fún un; ẹ̀kẹrin sì ni Adonijah ọmọ Haggiti; Ẹ̀karùnún ni Ṣefatia láti ọ̀dọ̀ Abitali; àti ẹ̀kẹfà, Itreamu, láti ọ̀dọ̀ Egla aya rẹ̀. Àwọn mẹ́fà wọ̀nyí ni a bí fún Dafidi ni Hebroni, níbi tí ó ti jẹ ọba fún ọdún méje àti oṣù mẹ́fà. Dafidi sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n (33). Wọ̀nyí ni ọmọ wẹ́wẹ́ tí a bí fún un ní Jerusalẹmu: Ṣimea, Ṣobabu, Natani àti Solomoni. Àwọn mẹ́rin wọ̀nyí sì ni a bí láti ọ̀dọ̀ Bati-Ṣua ọmọbìnrin Ammieli. Ibhari sì wà pẹ̀lú, Eliṣama, Elifeleti, Noga, Nefegi, Jafia, Eliṣama, Eliada àti Elifeleti mẹ́sàn-án ni wọ́n. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Dafidi yàtọ̀ sí àwọn ọmọ tí àlè bí fún un. Tamari sì ni arábìnrin wọn. Ọmọ Solomoni ni Rehoboamu, Abijah ọmọ rẹ̀, Asa ọmọ rẹ̀, Jehoṣafati ọmọ rẹ̀