I. Kro 29:10-20

I. Kro 29:10-20 Bibeli Mimọ (YBCV)

Nitorina Dafidi fi iyìn fun Oluwa li oju gbogbo ijọ: Dafidi si wipe, Olubukún ni Iwọ Oluwa Ọlọrun Israeli baba wa lai ati lailai! Tirẹ Oluwa ni titobi, ati agbara, ati ogo, ati iṣẹgun, ati ọlá-nla: nitori ohun gbogbo li ọrun ati li aiye tirẹ ni; ijọba ni tirẹ, Oluwa, a si gbé ọ leke li ori fun ohun gbogbo. Ọrọ̀ pẹlu ati ọlá ọdọ rẹ ni ti iwá, iwọ si jọba lori ohun gbogbo; li ọwọ rẹ ni agbara ati ipá wà; ati li ọwọ rẹ ni sisọ ni di nla wà, ati fifi agbara fun ohun gbogbo. Njẹ nisisiyi, Ọlọrun wa, awa dupẹ lọwọ rẹ, a si yìn orukọ ogo rẹ. Ṣugbọn tali emi, ati kili awọn enia mi, ti a fi le ṣe iranlọwọ tinutinu bi iru eyi? nitori ohun gbogbo ọdọ rẹ ni ti wá, ati ninu ohun ọwọ rẹ li awa ti fi fun ọ. Nitori alejo ni awa niwaju rẹ, ati atipo bi gbogbo awọn baba wa: ọjọ wa li aiye dabi ojiji, kò si si ireti. Oluwa Ọlọrun wa, gbogbo ohun ọ̀pọlọpọ yi ti awa ti pèse silẹ lati kọ ile fun ọ fun orukọ rẹ mimọ́, lati ọwọ rẹ wá ni, ati gbogbo rẹ̀ jẹ tirẹ. Emi mọ̀ pẹlu, Ọlọrun mi, pe iwọ ndan ọkàn wò, iwọ si ni inudidún si ododo. Bi o ṣe ti emi, ninu ododo ọkàn mi li emi ti fi tinutinu ṣe iranlọwọ gbogbo nkan wọnyi; ati nisisiyi pẹlu ayọ̀ ni mo ti ri awọn enia rẹ ti o wá nihin, lati fi tinutinu ṣe iranlọwọ fun ọ. Oluwa Ọlọrun Abrahamu, Isaaki ati Israeli, awọn baba wa, pa eyi mọ́ lailai sinu ete ironu ọkàn awọn enia rẹ, si fi idi ọkàn wọn mulẹ si ọdọ rẹ: Si fi ọkàn pipe fun Solomoni ọmọ mi lati pa ofin rẹ, ẹri rẹ, ati ilana rẹ mọ́, ati lati ṣe ohun gbogbo, ati lati kọ́ ãfin, fun eyi ti mo ti pèse silẹ. Dafidi si sọ fun gbogbo ijọ enia pe, Nisisiyi ẹ fi iyìn fun Oluwa Ọlọrun nyin. Gbogbo enia si fi iyìn fun Oluwa Ọlọrun awọn baba wọn, nwọn si tẹ ori wọn ba, nwọn wolẹ fun Oluwa ati ọba.

I. Kro 29:10-20 Yoruba Bible (YCE)

Nítorí náà, Dafidi yin OLUWA níwájú gbogbo eniyan, ó ní: “Ìyìn ni fún ọ títí lae, OLUWA, Ọlọrun Israẹli, Baba ńlá wa, OLUWA, o tóbi pupọ, tìrẹ ni agbára, ògo, ìṣẹ́gun, ati ọlá ńlá; nítorí tìrẹ ni ohun gbogbo ní ọ̀run ati ní ayé. Tìrẹ ni ìjọba, a gbé ọ ga bí orí fún ohun gbogbo. Láti ọ̀dọ̀ rẹ wá ni ọrọ̀ ati ọlá ti ń wá, o sì ń jọba lórí ohun gbogbo. Ìkáwọ́ rẹ ni ipá ati agbára wà, ó wà ní ìkáwọ́ rẹ láti gbéni ga ati láti fún ni lágbára. A dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Ọlọrun wa, a sì yin orúkọ rẹ tí ó lógo. “Ṣugbọn, kí ni mo jẹ́, kí sì ni àwọn eniyan mi jẹ́, tí a fi lè mú ọrẹ tí ó pọ̀ tó báyìí wá fún Ọlọrun tọkàntọkàn? Nítorí láti ọ̀dọ̀ rẹ ni ohun gbogbo ti wá, ninu ohun tí o fún wa ni a sì ti mú wá fún ọ. Àjèjì ati àlejò ni a jẹ́ ní ojú rẹ, gẹ́gẹ́ bí àwọn baba ńlá wa. Gbogbo ọjọ́ wa láyé dàbí òjìji, kò lè wà pẹ́ títí. OLUWA, Ọlọrun wa, tìrẹ ni gbogbo ohun tí a mú wá, láti fi kọ́ ilé fún orúkọ mímọ́ rẹ, ọ̀dọ̀ rẹ ni wọ́n sì ti wá. Ọlọrun mi, mo mọ̀ pé ò máa yẹ ọkàn wò, o sì ní inú dídùn sí òtítọ́; tọkàntọkàn mi ni mo fi mú gbogbo nǹkan wọnyi wá fún ọ, mo sì ti rí i bí àwọn eniyan rẹ ti fi tọkàntọkàn ati inú dídùn mú ọrẹ wọn wá fún ọ. OLUWA Ọlọrun àwọn baba wa: Abrahamu, Isaaki ati Israẹli, jẹ́ kí irú ẹ̀mí yìí túbọ̀ máa wà ninu àwọn eniyan rẹ títí lae, kí o sì jẹ́ kí ọkàn wọn máa fà sí ọ̀dọ̀ rẹ. Jọ̀wọ́, jẹ́ kí Solomoni ọmọ mi, fi gbogbo ọkàn rẹ̀ pa òfin, àṣẹ ati ìlànà rẹ mọ́, kí ó lè ṣe ohun gbogbo, kí ó sì lè kọ́ tẹmpili tí mo ti múra rẹ̀ sílẹ̀ fún.” Dafidi sọ fún gbogbo ìjọ eniyan pé, “Ẹ yin OLUWA Ọlọrun yín.” Gbogbo wọn bá yin OLUWA Ọlọrun àwọn baba wọn. Wọ́n wólẹ̀, wọ́n sin OLUWA, wọ́n sì tẹríba fún ọba.

I. Kro 29:10-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Dafidi yin OLúWA níwájú gbogbo àwọn tí ó péjọ, wí pé, “Ìyìn ni fún Ọ, OLúWA, Ọlọ́run baba a wa Israẹli, láé àti láéláé. Tìrẹ OLúWA ni títóbi àti agbára pẹ̀lú ìyìn àti ọláńlá àti dídán, nítorí tí gbogbo nǹkan ní ọ̀run àti ayé jẹ́ tìrẹ. Tìrẹ OLúWA ni ìjọba; a gbé ọ ga gẹ́gẹ́ bí orí lórí ohun gbogbo. Ọlá àti ọ̀wọ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Rẹ; ìwọ ni alákòóso gbogbo nǹkan. Ní ọwọ́ rẹ ni ipá àti agbára wà láti gbéga àti láti fi agbára fún ohun gbogbo. Nísinsin yìí, Ọlọ́run wa, àwa fi ọpẹ́ fún Ọ, a sì fi ìyìn fún orúkọ rẹ̀ tí ó lógo. “Ṣùgbọ́n ta ni èmi, àti ta ni àwọn ènìyàn mi, tí a fi lè ṣe ìrànlọ́wọ́ tinútinú bí irú èyí? Gbogbo nǹkan wá láti ọ̀dọ̀ rẹ ní ti wá, àwa sì ti fífún ọ láti ara ohun tí ó wá láti ọwọ́ rẹ. Àwa jẹ́ àjèjì àti àlejò ní ojú rẹ gẹ́gẹ́ bí baba ńlá a wa, àwọn ọjọ́ wa lórí ilẹ̀ ayé rí bí òjìji láìsí ìrètí. OLúWA Ọlọ́run wa tí fi gbogbo púpọ̀ yìí tí àwa ti pèsè fún kíkọ́ ilé OLúWA fun orúkọ, mímọ́ rẹ̀, ó wá láti ọwọ́ ọ̀ rẹ, gbogbo rẹ̀ sì jẹ́ tirẹ̀. Èmi mọ̀ Ọlọ́run mi, wí pé ìwọ̀ dán ọkàn wò, ó sì tẹ́ ọ lọ́rùn pẹ̀lú òtítọ́ inú. Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni èmi ti fi sílẹ̀ pẹ̀lú tìfẹ́tìfẹ́ pẹ̀lú òtítọ́. Nísinsin yìí èmi ti rí i pẹ̀lú ayọ̀ bí àwọn ènìyàn yìí tí ó wà níbí ti fi fún ọ pẹ̀lú tìfẹ́tìfẹ́. OLúWA Ọlọ́run àwọn baba a wa Abrahamu, Isaaki àti Israẹli pa ìfẹ́ yìí mọ́ nínú ọkàn àwọn ènìyàn rẹ títí láé pẹ̀lú pípa ọkàn mọ́ lóòtítọ́ sí ọ. Àti fún ọmọ mi Solomoni ní ìfọkànsìn tòótọ́ láti pa àṣẹ rẹ mọ́ àwọn ohun tí ó nílò àti òfin àti láti ṣe ohun gbogbo láti kọ́ ààfin bí ti ọba fún èyí tí mo ti pèsè.” Dafidi sì sọ fún gbogbo ìjọ ènìyàn pé, Nísinsin yìí, ẹ fi ìyìn fún OLúWA Ọlọ́run yín. Gbogbo ènìyàn sì fi ìyìn fún OLúWA Ọlọ́run àwọn baba wọn, wọ́n sì tẹ orí wọn ba, wọ́n wólẹ̀ fún OLúWA àti ọba.

I. Kro 29:10-20

I. Kro 29:10-20 YBCVI. Kro 29:10-20 YBCVI. Kro 29:10-20 YBCV