I. Kro 2:5-10
I. Kro 2:5-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
Awọn ọmọ Faresi; Hesroni; ati Hamuli. Ati awọn ọmọ Sera; Simri, ati Etani, ati Hemani, ati Kalkoli, ati Dara: gbogbo wọn jẹ marun. Ati awọn ọmọ Karmi; Akari, oniyọnu Israeli, ẹniti o dẹṣẹ niti ohun iyasọtọ̀. Awọn ọmọ Etani; Asariah. Awọn ọmọ Hesroni pẹlu ti a bi fun u; Jerahmeeli, ati Ramu, ati Kelubai. Ramu si bi Amminadabu; Amminadabu si bi Naṣoni, ijoye awọn ọmọ Juda
I. Kro 2:5-10 Yoruba Bible (YCE)
Àwọn ọmọ Peresi ni Hesironi ati Hamuli. Sera bí ọmọ marun-un: Simiri, Etani, Hemani, Kalikoli ati Dada. Kami ni baba Akani; Akani yìí ni ó kó wahala bá Israẹli, nítorí pé ó rú òfin nípa àwọn ohun ìyàsọ́tọ̀. Etani ni ó bí Asaraya. Àwọn ọmọ Hesironi ni Jerameeli, Ramu ati Kelubai. Ramu bí Aminadabu, Aminadabu bi Naṣoni, olórí pataki ninu ẹ̀yà Juda
I. Kro 2:5-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àwọn ọmọ Peresi: Hesroni àti Hamulu. Àwọn ọmọ Sera: Simri, Etani, Hemani, Kalkoli àti Dara, gbogbo wọn jẹ́ márùn-ún. Àwọn ọmọ Karmi: Akani, ẹni tí ó mú ìyọnu wá sórí Israẹli nípa ẹ̀ṣẹ̀ ìfibú lórí mímú ohun ìyàsọ́tọ̀. Àwọn ọmọ Etani: Asariah. Àwọn ọmọ tí a bí fún Hesroni ni: Jerahmeeli, Ramu àti Kalebu. Ramu sì ni baba Amminadabu, àti Amminadabu baba Nahiṣoni olórí àwọn ènìyàn Juda.