I. Kro 2:1-55

I. Kro 2:1-55 Bibeli Mimọ (YBCV)

WỌNYI ni awọn ọmọ Israeli; Rubeni, Simeoni, Lefi, ati Juda, Issakari, ati Sebuluni, Dani, Josefu, ati Benjamini, Naftali, Gadi, ati Aṣeri. Awọn ọmọ Juda; Eri, ati Onani, ati Ṣela; awọn mẹta yi ni Batṣua, ara Kenaani, bi fun u. Eri, akọbi Juda, si buru loju Oluwa; on si pa a. Tamari aya-ọmọ rẹ̀ si bi Faresi ati Sera fun u. Gbogbo awọn ọmọ Juda jẹ marun. Awọn ọmọ Faresi; Hesroni; ati Hamuli. Ati awọn ọmọ Sera; Simri, ati Etani, ati Hemani, ati Kalkoli, ati Dara: gbogbo wọn jẹ marun. Ati awọn ọmọ Karmi; Akari, oniyọnu Israeli, ẹniti o dẹṣẹ niti ohun iyasọtọ̀. Awọn ọmọ Etani; Asariah. Awọn ọmọ Hesroni pẹlu ti a bi fun u; Jerahmeeli, ati Ramu, ati Kelubai. Ramu si bi Amminadabu; Amminadabu si bi Naṣoni, ijoye awọn ọmọ Juda; Naṣoni si bi Salma, Salma si bi Boasi. Boasi si bi Obedi, Obedi si bi Jesse, Jesse si bi Eliabu akọbi rẹ̀, ati Abinadabu àtẹle, ati Ṣimma ẹkẹta. Netanneeli ẹkẹrin, Raddai ẹkarun, Osemu ẹkẹfa, Dafidi ekeje: Awọn arabinrin wọn ni Seruiah ati Abigaili. Ati awọn ọmọ Seruiah; Abiṣai, ati Joabu, ati Asaeli, mẹta. Abigaili si bi Amasa: baba Amasa si ni Jeteri ara Iṣmeeli. Kalebu ọmọ Hesroni si bi ọmọ lati ọdọ Asuba aya rẹ̀, ati lati ọdọ Jeriotu: awọn ọmọ rẹ̀ ni wọnyi; Jeṣeri, ati Ṣohabu, ati Ardoni. Nigbati Asuba kú, Kalebu mu Efrati, ẹniti o bi Huri fun u. Huri si bi Uru, Uru si bi Besaleeli. Lẹhin na Hesroni si wọle tọ̀ ọmọ Makiri obinrin baba Gileadi, on gbe e ni iyawo nigbati o di ẹni ọgọta ọdun, on si bi Segubu fun u. Segubu si bi Jairi, ti o ni ilu mẹtalelogun ni ilẹ Gileadi. Ṣugbọn Geṣuri, ati Aramu, gbà ilu Jairi lọwọ wọn, pẹlu Kenati, ati ilu rẹ̀: ani ọgọta ilu. Gbogbo wọnyi ni awọn ọmọ Makiri baba Gileadi. Ati lẹhin igbati Hesroni kú ni ilu Kaleb-Efrata, ni Abiah aya Hesroni bi Aṣuri baba Tekoa fun u. Ati awọn ọmọ Jerahmeeli, akọbi Hesroni, ni Rama akọbi, ati Buna, ati Oreni, ati Osemu, ati Ahijah. Jerahmeeli si ni obinrin miran pẹlu, orukọ ẹniti ijẹ Atara; on ni iṣe iya Onamu. Awọn ọmọ Ramu akọbi Jerahmeeli ni, Maasi, ati Jamini, ati Ekeri. Awọn ọmọ Onamu si ni, Ṣammai, ati Jada. Awọn ọmọ Ṣammai ni; Nadabu ati Abiṣuri. Orukọ aya Abiṣuri si njẹ Abihaili, on si bi Abani, ati Molidi fun u. Ati awọn ọmọ Nadabu; Seledi, ati Appaimu: ṣugbọn Seledi kú laini ọmọ. Ati awọn ọmọ Appaimu; Iṣi. Ati awọn ọmọ Iṣi; Ṣeṣani. Ati awọn ọmọ Ṣeṣani. Ahlai. Ati awọn ọmọ Jada arakunrin Ṣammai; Jeteri, ati Jonatani; Jeteri si kú laini ọmọ. Awọn ọmọ Jonatani; Peleti, ati Sasa. Wọnyi ni awọn ọmọ Jerahmeeli. Ṣeṣani kò si ni ọmọkunrin, bikọṣe ọmọbinrin. Ṣeṣani si ni iranṣẹ kan, ara Egipti, orukọ, ẹniti ijẹ Jarha. Ṣeṣani si fi ọmọbinrin rẹ̀ fun Jarha iranṣẹ rẹ̀ li aya; on si bi Attai fun u. Attai si bi Natani, Natani si bi Sabadi, Sabadi si bi Eflali, Eflali si bi Obedi, Obedi si bi Jehu, Jehu si bi Asariah, Asariah si bi Helesi, Helesi si bi Elasa, Elasa si bi Sisamai, Sisamai si bi Ṣallumu, Ṣallumu si bi Jekamiah, Jekamiah si bi Eliṣama. Awọn ọmọ Kalebu arakunrin Jerahmeeli si ni Meṣa akọbi rẹ̀, ti iṣe baba Sifi; ati awọn ọmọ Mareṣa baba Hebroni. Awọn ọmọ Hebroni; Kora, ati Tappua, ati Rekemu, ati Ṣema. Ṣema si bi Rahamu, baba Jorkeamu: Rekemu si bi Ṣammai. Ati ọmọ Ṣammai ni Maoni: Maoni si ni baba Bet-suri. Efa obinrin Kalebu si bi Harani, ati Mosa, ati Gasesi: Harani si bi Gasesi. Ati awọn ọmọ Jahdai; Regemu, ati Jotamu, ati Geṣamu, ati Peleti, ati Efa, ati Ṣaafu. Maaka obinrin Kalebu bi Ṣeberi, ati Tirhana. On si bi Ṣaafa baba Madmana, Ṣefa baba Makbena, ati baba Gibea: ọmọbinrin Kalebu si ni Aksa. Wọnyi li awọn ọmọ Kalebu ọmọ Huri, akọbi Efrata; Ṣobali baba Kirjat-jearimu, Salma baba Bet-lehemu, Harefu baba Bet-gaderi. Ati Ṣobali baba Kirjat-jearimu ni ọmọ; Haroe, ati idaji awọn ara Manaheti. Ati awọn idile Kirjat-jearimu; awọn ara Itri, ati awọn ara Puti, ati awọn ara Ṣummati, ati awọn ara Misrai; lọdọ wọn li awọn ara Sareati, ati awọn ara Ẹstauli ti wá. Awọn ọmọ Salma; Betlehemu, ati awọn ara Netofati, Ataroti, ile Joabu, ati idaji awọn ara Manahati, awọn ara Sori. Ati idile awọn akọwe ti ngbe Jabesi; awọn ara Tira, awọn ara Ṣimeati, ati awọn ara Sukati. Wọnyi li awọn ara Keni ti o ti ọdọ Hemati wá, baba ile Rekabu.

I. Kro 2:1-55 Yoruba Bible (YCE)

Àwọn ọmọ Israẹli nìwọ̀nyí: Reubẹni, Simeoni, ati Lefi; Juda, Isakari, ati Sebuluni; Dani, Josẹfu, ati Bẹnjamini; Nafutali, Gadi ati Aṣeri. Juda bí ọmọ marun-un. Batiṣua, aya rẹ̀, ará Kenaani, bí ọmọ mẹta fún un: Eri, Onani ati Ṣela. Eri, àkọ́bí Juda, jẹ́ eniyan burúkú lójú OLUWA, OLUWA bá pa á. Tamari, iyawo ọmọ Juda, bí ọmọ meji fún un: Peresi ati Sera. Àwọn ọmọ Peresi ni Hesironi ati Hamuli. Sera bí ọmọ marun-un: Simiri, Etani, Hemani, Kalikoli ati Dada. Kami ni baba Akani; Akani yìí ni ó kó wahala bá Israẹli, nítorí pé ó rú òfin nípa àwọn ohun ìyàsọ́tọ̀. Etani ni ó bí Asaraya. Àwọn ọmọ Hesironi ni Jerameeli, Ramu ati Kelubai. Ramu bí Aminadabu, Aminadabu bi Naṣoni, olórí pataki ninu ẹ̀yà Juda, Nahiṣoni ni baba Salima; Salima ni ó bí Boasi, Boasi bí Obedi, Obedi sì bí Jese. Jese bí ọmọ meje; orúkọ wọn nìyí bí wọ́n ṣe tẹ̀lé ara wọn: Eliabu ni àkọ́bí, lẹ́yìn náà Abinadabu ati Ṣimea; Netaneli ati Radai; Osemu ati Dafidi. Àwọn arabinrin wọn ni Seruaya ati Abigaili. Seruaya yìí ló bí Abiṣai, Joabu ati Asaheli. Abigaili fẹ́ Jeteri láti inú ìran Iṣimaeli, ó sì bí Amasa fún un. Hesironi ni baba Kalebu. Asuba (ati Jeriotu) ni aya Kalebu yìí, Asuba bí ọmọkunrin mẹta fún un: Jeseri, Ṣobabu, ati Aridoni. Nígbà tí Asuba kú, Kalebu fẹ́ Efurati, Efurati sì bí Huri fún un. Huri ni ó bí Uri, Uri sì bí Besaleli. Nígbà tí Hesironi di ẹni ọgọta ọdún, ó fẹ́ ọmọbinrin Makiri, baba Gileadi. Ọmọbinrin yìí sì bí ọmọkunrin kan fún un tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Segubu. Segubu ni ó bí Jairi, tí ó jọba lórí ìlú ńláńlá mẹtalelogun ní ilẹ̀ Gileadi. Ṣugbọn Geṣuri ati Aramu gba Hafoti Jairi lọ́wọ́ rẹ̀, ati Kenati ati àwọn ìletò tí ó wà ní àyíká rẹ̀; gbogbo wọn jẹ́ ọgọta ìlú. Gbogbo wọn jẹ́ arọmọdọmọ Makiri, baba Gileadi. Lẹ́yìn ìgbà tí Hesironi kú, Kalebu ṣú Efurata, iyawo baba rẹ̀ lópó, ó sì bí Aṣuri, tíí ṣe baba Tekoa. Jerameeli, àkọ́bí Hesironi, bí ọmọkunrin marun-un: Ramu ni àkọ́bí, lẹ́yìn rẹ̀ ni wọ́n bí Buna, Oreni, Osemu, ati Ahija. Jerameeli tún ní aya mìíràn, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Atara, òun ni ìyá Onamu. Àwọn ọmọ Ramu, àkọ́bí Jerameeli ni: Maasi, Jamini ati Ekeri. Onamu bí ọmọ meji: Ṣamai ati Jada. Ṣamai náà bí ọmọ meji: Nadabu ati Abiṣuri. Orúkọ aya Abiṣuri ni Abihaili, ó sì bí Ahibani ati Molidi fún un. Nadabu, arakunrin Abiṣuri náà bí ọmọ meji: Seledi ati Apaimu; ṣugbọn Seledi kò bímọ títí tí ó fi kú. Apaimu ni baba Iṣi. Iṣi bí Ṣeṣani, Ṣeṣani sì bí Ahilai. Jada, arakunrin Ṣamai, bí ọmọ meji: Jeteri ati Jonatani, ṣugbọn Jeteri kò bímọ títí tí ó fi kú. Jonatani bí ọmọ meji: Peleti ati Sasa. Àwọn ni ìran Jerameeli. Ṣeṣani kò bí ọmọkunrin kankan, kìkì ọmọbinrin ni ó bí; ṣugbọn Ṣeṣani ní ẹrú kan, ará Ijipti, tí ń jẹ́ Jariha. Ṣeṣani fi ọmọ rẹ̀ obinrin fún Jariha, ẹrú rẹ̀, ó sì bí Atai fún ẹrú náà. Atai ni baba Natani, Natani sì ni baba Sabadi. Sabadi bí Efiali, Efiali sì bí Obedi. Obedi ni baba Jehu, Jehu sì ni baba Asaraya. Asaraya ni ó bí Helesi, Helesi ni ó sì bí Eleasa. Eleasa bí Sisimai, Sisimai bí Ṣalumu; Ṣalumu bí Jekamaya, Jekamaya sì bí Eliṣama. Àwọn ọmọ Kalebu, arakunrin Jerameeli, nìwọ̀nyí: Mareṣa, baba Sifi ni àkọ́bí rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó bí Heburoni. Heburoni bí ọmọ mẹrin: Kora, Tapua, Rekemu ati Ṣema. Ṣema bí Rahamu, Rahamu bí Jokeamu, Rekemu sì bí Ṣamai. Ṣamai ló bí Maoni, Maoni sì bí Betisuri. Kalebu tún ní obinrin kan tí ń jẹ́ Efa, ó bí ọmọ mẹta fún un: Harani, Mosa ati Gasesi. Harani bí ọmọ kan tí ń jẹ́ Gasesi. Àwọn ọmọ Jadai nìwọ̀nyí: Regemu, Jotamu, ati Geṣani, Peleti, Efa ati Ṣaafu. Kalebu tún ní obinrin mìíràn tí ń jẹ́ Maaka. Ó bí ọmọ meji fún un: Ṣeberi ati Tirihana. Maaka yìí kan náà ni ó bí Ṣaafu, baba Madimana, tí ó tẹ ìlú Madimana dó, ati Ṣefa, baba Makibena ati Gibea, àwọn ni wọ́n tẹ ìlú Makibena ati ìlú Gibea dó. Kalebu tún bí ọmọbinrin kan tí ń jẹ́ Akisa. Àwọn ìran Kalebu yòókù ni: àwọn ọmọ Huri àkọ́bí Efurata, iyawo Kalebu: ati Ṣobali, baba Kiriati Jearimu; Salima, baba Bẹtilẹhẹmu, ati Harefu baba Betigaderi. Ṣobali baba Kiriati Jearimu ni baba gbogbo àwọn ará Haroe, ati ìdajì àwọn tí ń gbé Menuhotu, Òun náà ni baba ńlá gbogbo àwọn ìdílé tí ń gbé Kiriati Jearimu, àwọn ìdílé bíi Itiri, Puti, Ṣumati, ati Miṣirai; lára wọn ni àwọn tí wọn ń gbé ìlú Sora ati Eṣitaolu ti ṣẹ̀. Salima ni baba àwọn ará Bẹtilẹhẹmu, Netofati, ati ti Atirotu Beti Joabu; àwọn ará Soriti ati ìdajì àwọn ará Manahati. Àwọn ìdílé àwọn akọ̀wé tí wọn ń gbé Jabesi nìyí: àwọn ará Tirati, Ṣimeati, ati Sukati. Àwọn ni ará Keni tí wọ́n ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Hamati baba ńlá wọn ní ilé Rekabu.

I. Kro 2:1-55 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Israẹli. Reubeni, Simeoni, Lefi, Juda, Isakari, Sebuluni, Dani, Josẹfu, Benjamini; Naftali, Gadi: àti Aṣeri. Àwọn ọmọ Juda: Eri, Onani àti Ṣela, àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí ni wọ́n bí fún un láti ọ̀dọ̀ arábìnrin Kenaani, ọmọbìnrin Ṣua. Eri àkọ́bí Juda, ó sì burú ní ojú OLúWA; Bẹ́ẹ̀ ni OLúWA sì pa á. Tamari, aya ọmọbìnrin Juda, ó sì bí Peresi àti Sera sì ní ọmọ márùn-ún ní àpapọ̀. Àwọn ọmọ Peresi: Hesroni àti Hamulu. Àwọn ọmọ Sera: Simri, Etani, Hemani, Kalkoli àti Dara, gbogbo wọn jẹ́ márùn-ún. Àwọn ọmọ Karmi: Akani, ẹni tí ó mú ìyọnu wá sórí Israẹli nípa ẹ̀ṣẹ̀ ìfibú lórí mímú ohun ìyàsọ́tọ̀. Àwọn ọmọ Etani: Asariah. Àwọn ọmọ tí a bí fún Hesroni ni: Jerahmeeli, Ramu àti Kalebu. Ramu sì ni baba Amminadabu, àti Amminadabu baba Nahiṣoni olórí àwọn ènìyàn Juda. Nahiṣoni sì ni baba Salmoni, Salmoni ni baba Boasi, Boasi baba Obedi àti Obedi baba Jese. Jese sì ni baba Eliabu àkọ́bí rẹ̀; ọmọ ẹlẹ́kejì sì ni Abinadabu, ẹlẹ́kẹta ni Ṣimea, Ẹlẹ́kẹrin Netaneli, ẹlẹ́karùnún Raddai, ẹlẹ́kẹfà Osemu àti ẹlẹ́keje Dafidi. Àwọn arábìnrin wọn ni Seruiah àti Abigaili. Àwọn ọmọ mẹ́ta Seruiah ni Abiṣai, Joabu àti Asaheli. Abigaili ni ìyá Amasa, ẹni tí baba rẹ̀ sì jẹ́ Jeteri ará Iṣmaeli. Kalebu ọmọ Hesroni ní ọmọ láti ọ̀dọ̀ ìyàwó rẹ̀ Asuba (láti ọ̀dọ̀ Jerioti). Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ rẹ̀: Jeṣeri, Ṣobabu àti Ardoni. Nígbà tí Asuba sì kú, Kalebu sì fẹ́ Efrata ní aya, ẹni tí ó bí Huri fún un. Huri ni baba Uri, Uri sì jẹ́ baba Besaleli. Nígbà tí ó yá, Hesroni sì dùbúlẹ̀ pẹ̀lú ọmọbìnrin Makiri baba Gileadi (ó sì ti fẹ́ ní aya láti ìgbà tí ó ti wà ní ẹni ọgọ́ta ọdún) ó sì bí Segubu. Segubu sì jẹ́ baba Jairi, ẹni tí ó jẹ́ olùdarí ìlú mẹ́tàlélógún ní ilẹ̀ Gileadi. (Ṣùgbọ́n Geṣuri àti Aramu sì fi agbára gba Hafoti-Jairi, àti Kenati pẹ̀lú gbogbo agbègbè rẹ̀ tí wọn tẹ̀dó sí jẹ́ ọgọ́ta ìlú.) Gbogbo wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Makiri Baba Gileadi. Lẹ́yìn tí Hesroni sì kú ni Kalebu Efrata, Abijah ìyàwó rẹ̀ ti Hesroni sì bí Aṣihuri baba Tekoa fún un. Ọmọ Jerahmeeli àkọ́bí Hesroni: Ramu ọmọ àkọ́bí rẹ̀ Buna, Oreni, Osemu àti Ahijah. Jerahmeeli ní ìyàwó mìíràn, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Atara; ó sì jẹ́ ìyá fún Onamu. Àwọn ọmọ Ramu àkọ́bí Jerahmeeli: Maasi, Jamini àti Ekeri. Àwọn ọmọ Onamu: Ṣammai àti Jada. Àwọn ọmọ Ṣammai: Nadabu àti Abiṣuri. Orúkọ ìyàwó Abiṣuri ni Abihaili ẹni tí ó bí Ahbani àti Molidi. Àwọn ọmọ Nadabu Ṣeledi àti Appaimu. Ṣeledi sì kú láìsí ọmọ. Àwọn ọmọ Appaimu: Iṣi, ẹni tí ó jẹ́ baba fún Ṣeṣani. Ṣeṣani sì jẹ́ baba fún Ahlai. Àwọn ọmọ Jada, arákùnrin Ṣammai: Jeteri àti Jonatani. Jeteri sì kú láìní ọmọ. Àwọn ọmọ Jonatani: Peleti àti Sasa. Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Jerahmeeli. Ṣeṣani kò sì ní ọmọkùnrin àwọn ọmọbìnrin nìkan ni ó ní. Ó sì ní ìránṣẹ́ ará Ejibiti tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jariha. Ṣeṣani sì fi ọmọ obìnrin rẹ̀ ní aya fún ìránṣẹ́ rẹ̀ Jariha, ó sì bí ọmọ fún tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ Attai. Attai sì jẹ́ baba fún Natani, Natani sì jẹ́ baba fún Sabadi, Sabadi ni baba Eflali, Eflali jẹ́ baba Obedi, Obedi sì ni baba Jehu, Jehu ni baba Asariah, Asariah sì ni baba Helesi, Helesi ni baba Eleasa, Eleasa ni baba Sismai, Sismai ni baba Ṣallumu, Ṣallumu sì ni baba Jekamiah, Jekamiah sì ni baba Eliṣama. Àwọn ọmọ Kalebu arákùnrin Jerahmeeli: Meṣa àkọ́bí rẹ̀, ẹni tí ó jẹ́ baba fún Sifi, àti àwọn ọmọ rẹ̀ Meraṣa, ẹni tí ó jẹ́ baba fún Hebroni. Àwọn ọmọ Hebroni: Kora, Tapua, Rekemu, àti Ṣema. Ṣema ni baba Rahamu, Rahamu sì jẹ́ baba fún Jorkeamu. Rekemu sì ni baba Ṣammai. Àwọn ọmọ Ṣammai ni Maoni, Maoni sì ni baba Beti-Suri. Efani obìnrin Kalebu sì ni ìyá Harani, Mosa àti Gasesi, Harani sì ni baba Gasesi. Àwọn ọmọ Jahdai: Regemu, Jotamu, Geṣani, Peleti, Efani àti Ṣaafa. Maaka obìnrin Kalebu sì ni ìyá Seberi àti Tirhana. Ó sì bí Ṣaafa baba Madmana, Ṣefa baba Makbena àti baba Gibeah. ọmọbìnrin Kalebu sì ni Aksa. Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Kalebu. Àwọn ọmọ Huri, àkọ́bí Efrata: Ṣobali baba Kiriati-Jearimu. Salma baba Bẹtilẹhẹmu àti Harefu baba Beti-Gaderi. Àwọn ọmọ Ṣobali baba Kiriati-Jearimu ni: Haroe, ìdajì àwọn ará Manaheti. Àti ìdílé Kiriati-Jearimu: àti àwọn ara Itri, àti àwọn ará Puti, àti àwọn ará Ṣumati àti àwọn ará Miṣraiti: láti ọ̀dọ̀ wọn ni àwọn ọmọ ará Sorati àti àwọn ará Eṣtaoli ti wá. Àwọn ọmọ Salma: Bẹtilẹhẹmu, àti àwọn ará Netofa, Atrotu Beti-Joabu, ìdajì àwọn ará Manahati, àti ará Sori, Àti àwọn ìdílé àwọn akọ̀wé, ẹni tí ń gbé ní Jabesi: àti àwọn ọmọ Tirati àti àwọn ará Ṣimeati àti àwọn ará Sukati. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ará Keni, ẹni tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Hamati, baba ilé Rekabu.