Ọ̀rọ̀ OLúWA àwọn ọmọ-ogun si tún tọ́ mí wá. Báyìí ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí: “Owú ńláńlá ni mo jẹ fún Sioni, pẹ̀lú ìbínú ńláńlá ni mo fi jowú fún un.” Báyìí ni OLúWA wí: “Mo yípadà sí Sioni èmi ó sì gbé àárín Jerusalẹmu: Nígbà náà ni a ó sì pé Jerusalẹmu ni ìlú ńlá òtítọ́; àti òkè ńlá OLúWA àwọn ọmọ-ogun, ni a ó pè ní òkè ńlá mímọ́.” Báyìí ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí: “Arúgbó ọkùnrin, àti arúgbó obìnrin, yóò gbé ìgboro Jerusalẹmu, àti olúkúlùkù pẹ̀lú ọ̀pá ni ọwọ́ rẹ̀ fún ogbó. Ìgboro ìlú yóò sì kún fún ọmọdékùnrin, àti ọmọdébìnrin, tí ń ṣiré ní ìta wọn.” Báyìí ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí pé: “Bí ó bá ṣe ìyanu ní ojú ìyókù àwọn ènìyàn yìí ni ọjọ́ wọ̀nyí, ǹjẹ́ ó ha lè jẹ́ ìyanu ni ojú mi bí?” ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí. Báyìí ní OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí pé: “Kíyèsi i, èmi ó gba àwọn ènìyàn mi kúrò ni ilẹ̀ ìlà-oòrùn, àti kúrò ni ilẹ̀ ìwọ̀-oòrùn. Èmi ó sì mú wọn padà wá, wọn ó sì máa gbé àárín Jerusalẹmu. Wọn ó sì jẹ́ ènìyàn mi, èmi ó sì jẹ́ Ọlọ́run wọn, ní òtítọ́, àti ní òdodo.”
Kà Sekariah 8
Feti si Sekariah 8
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Sekariah 8:1-8
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò