Ní ọjọ́ kan, Naomi, ìyá ọkọ Rutu wí fún un pé, “Ọmọbìnrin mi, ǹjẹ́ kò yẹ kí èmi bá ọ wá ilé ọkọ mìíràn, níbi tí wọn yóò ti le è máa tọ́jú rẹ? Wò ó, Boasi ọkùnrin nì tí ìwọ bá àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ ṣiṣẹ́, tí í ṣe ìbátan wa, yóò wá láti fẹ́ ọkà barle ní ilẹ̀ ìpakà rẹ̀ ní àṣálẹ́ yìí. Wẹ̀, kí o sì fi ìpara olóòórùn dídùn pa ara rẹ, kí o sì wọ aṣọ rẹ tí ó dára jùlọ, kí o sì lọ sí ilẹ̀ ìpakà tí ó gbé ń pa ọkà, ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí ó mọ̀ pé o wà níbẹ̀ títí tí yóò fi jẹ tí yóò sì mu tán. Rí í dájú pé o mọ ibi tí ó sùn sí, lẹ́yìn ìgbà tí ó bá ti sùn, lọ kí o ṣí aṣọ ìbora rẹ̀ níbi ẹsẹ̀ rẹ̀ sókè kí o sì sùn sí ibi ẹsẹ̀ náà. Òun yóò sì sọ ohun tí ìwọ yóò ṣe fún ọ.” Rutu sì fèsì pé, “Gbogbo ohun tí ìwọ sọ fún mi ni èmi yóò ṣe.”
Kà Rutu 3
Feti si Rutu 3
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Rutu 3:1-5
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò