Èmi yóò gbé ọ ga, Ọlọ́run ọba mi; Èmi yóò yin orúkọ rẹ̀ láé àti láéláé Ní ojoojúmọ́ èmi yóò yìn ọ́ èmi yóò sì pòkìkí orúkọ rẹ láé àti láéláé. Títóbi ni OLúWA. Òun sì ni ó yẹ láti fi ìyìn fún púpọ̀púpọ̀: kò sí ẹni tí ó lè wọn títóbi rẹ̀. Ìran kan yóò máa yin iṣẹ́ rẹ dé ìran mìíràn; wọn yóò máa sọ iṣẹ́ agbára rẹ Wọn yóò máa sọ ìyìn ọláńlá rẹ tí ó lógo, èmi yóò máa ṣe àṣàrò nínú iṣẹ́ ìyanu rẹ. Wọn yóò sọ iṣẹ́ agbára rẹ tí ó ní ẹ̀rù èmi yóò kéde iṣẹ́ ńlá rẹ̀. Wọn yóò ṣe ìrántí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwà rere rẹ àti orin ayọ̀ òdodo rẹ. Olóore-ọ̀fẹ́ ni OLúWA àti aláàánú ó lọ́ra láti bínú ó sì ní ìfẹ́ púpọ̀. OLúWA dára sí ẹni gbogbo; ó ní àánú lórí ohun gbogbo tí ó dá.
Kà Saamu 145
Feti si Saamu 145
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Saamu 145:1-9
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò