Saamu 139:1-16

Saamu 139:1-16 YCB

OLúWA, ìwọ tí wádìí mi, ìwọ sì ti mọ̀ mí. Ìwọ mọ̀ ìjókòó mi àti ìdìde mi, ìwọ mọ̀ èrò mi ní ọ̀nà jíjìn réré. Ìwọ yí ipa ọ̀nà mi ká àti ìdùbúlẹ̀ mi, gbogbo ọ̀nà mi sì di mí mọ̀ fún ọ. Nítorí tí kò sí ọ̀rọ̀ kan ní ahọ́n mi, kíyèsi i, OLúWA, ìwọ mọ̀ ọ́n pátápátá. Ìwọ sé mi mọ́ lẹ́yìn àti níwájú, ìwọ sì fi ọwọ́ rẹ lé mi. Irú ìmọ̀ yìí jẹ ohun ìyanu fún mi jù; ó ga, èmi kò le mọ̀ ọ́n. Níbo ní èmi yóò gbé lọ kúrò ni ọwọ́ ẹ̀mí rẹ? Tàbí níbo ni èmi yóò sáré kúrò níwájú rẹ? Bí èmi bá gòkè lọ sí ọ̀run, ìwọ wà níbẹ̀; bí èmí ba sì tẹ́ ẹní mi ní ipò òkú, kíyèsi i, ìwọ wà níbẹ̀ pẹ̀lú. Èmi ìbá mú ìyẹ́ apá òwúrọ̀, kí èmi sì lọ jókòó ní ìhà òpin Òkun; Àní, níbẹ̀ náà ni ọwọ́ rẹ̀ yóò fà mí ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò sì dì mímú. Bí mo bá wí pé, “Ǹjẹ́ kí òkùnkùn kí ó bò mí mọ́lẹ̀; kí ìmọ́lẹ̀ kí ó di òru yí mi ká.” Nítòótọ́ òkùnkùn kì í ṣú lọ́dọ̀ rẹ; ṣùgbọ́n òru tan ìmọ́lẹ̀ bí ọ̀sán; àti òkùnkùn àti ọ̀sán, méjèèjì bákan náà ní fún ọ. Nítorí ìwọ ni ó dá ọkàn mi; ìwọ ni ó bò mí mọ́lẹ̀ nínú ìyá mi. Èmi yóò yìn ọ, nítorí tẹ̀rù tẹ̀rù àti tìyanu tìyanu ní a dá mi; ìyanu ní iṣẹ́ rẹ; èyí nì ni ọkàn mi sì mọ̀ dájúdájú Ẹ̀dá ara mi kò pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ rẹ, nígbà tí a dá mi ní ìkọ̀kọ̀. Tí a sì ń ṣiṣẹ́ ní àràbarà ní ìhà ìsàlẹ̀ ilẹ̀ ayé, ojú rẹ ti rí ohun ara mi nígbà tí a kò tí ì ṣe mí pé: àti nínú ìwé rẹ ni a ti kọ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sí, ní ọjọ́ tí a dá wọn, nígbà tí wọn kò tilẹ̀ tí ì sí.

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Saamu 139:1-16