Báwo ni èmi ti fẹ́ òfin rẹ tó! Èmi ń ṣe àṣàrò nínú rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ pípẹ́ wá. Àṣẹ rẹ mú mi gbọ́n ju àwọn ọ̀tá mi lọ, nítorí wọ́n wà pẹ̀lú mi láé. Èmi ní iyè inú ju gbogbo olùkọ́ mi lọ, nítorí èmi ń ṣe àṣàrò nínú òfin rẹ. Èmi ni òye ju àwọn àgbà lọ, nítorí mo gba ẹ̀kọ́ rẹ. Èmi ti pa ẹsẹ̀ mi mọ́ nínú gbogbo ọ̀nà ibi nítorí kí èmi lè gba ọ̀rọ̀ rẹ. Èmi kò yà kúrò nínú òfin rẹ, nítorí ìwọ fúnrarẹ̀ ni ó kọ́ mi. Báwo ni ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe dùn mọ́ mi lẹ́nu tó, ó dùn ju oyin lọ ní ẹnu mi! Èmi rí òye gbà nínú ẹ̀kọ́ rẹ; nítorí náà èmi kórìíra gbogbo ọ̀nà tí kò tọ́. OLúWA Ọ̀rọ̀ rẹ ni fìtílà sí ẹsẹ̀ mi àti ìmọ́lẹ̀ sí ipa ọ̀nà mi Èmi ti ṣe ìbúra èmi sì ti tẹnumọ́ ọn wí pé èmi yóò máa tẹ̀lé òfin òdodo rẹ.
Kà Saamu 119
Feti si Saamu 119
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Saamu 119:97-106
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò