Òwe 2:16-22

Òwe 2:16-22 YCB

Yóò gba ìwọ pẹ̀lú là kúrò lọ́wọ́ àwọn àjèjì obìnrin, àní, lọ́wọ́ obìnrin àjèjì tí ń fi ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ tannijẹ, ẹni tí ó ti kọ ọkọ àkọ́fẹ́ ìgbà èwe rẹ̀ sílẹ̀ tí ó sì gbàgbé májẹ̀mú tí ó ti dá níwájú Ọlọ́run rẹ̀. Nítorí ilé rẹ̀ jẹ́ ọ̀nà sí ikú ipa ọ̀nà rẹ̀ sọ́dọ̀ àwọn òkú. Kò sẹ́ni tó lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ tí ó padà bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í dé ọ̀nà ìyè. Bẹ́ẹ̀ ni ìwọ yóò rìn ní ọ̀nà àwọn ènìyàn rere kí ìwọ kí ó sì pa ọ̀nà àwọn olódodo mọ́. Nítorí ẹni dídúró ṣinṣin yóò gbé ní ilé náà àwọn aláìlẹ́gàn sì ni yóò máa wà nínú rẹ̀. Ṣùgbọ́n a ó ké ènìyàn búburú kúrò lórí ilẹ̀ náà a ó sì fa àwọn aláìṣòótọ́ tu kúrò lórí rẹ̀.