Òwe 14:22-24

Òwe 14:22-24 YCB

Ǹjẹ́ àwọn tí ń pète ibi kì í ṣìnà bí? Ṣùgbọ́n àwọn tí ń gbèrò ohun rere ń rí ìfẹ́ àti òtítọ́. Gbogbo iṣẹ́ àṣekára ló máa ń mú èrè wá, ṣùgbọ́n ẹjọ́ rírò lásán máa ń ta ni lósì ni. Ọrọ̀ ọlọ́gbọ́n ènìyàn ni adé orí wọn ṣùgbọ́n ìwà aláìgbọ́n ń mú ìwà òmùgọ̀ wá.