Òwe 1:20-23

Òwe 1:20-23 YCB

Ọgbọ́n kígbe sókè ní pópó ó gbé ohùn rẹ̀ sókè láàrín ọjà; Láàrín ọjà ni ó ti kígbe jáde Ní ibodè ìlú ni ó ti sọ̀rọ̀ ọ rẹ̀: “Yóò ha ti pẹ́ tó tí ẹ̀yin aláìmọ̀kan yóò fi fẹ́ àìmọ̀kan yín tó? Yóò ha ti pẹ́ tó tí àwọn ẹlẹ́gàn yóò ṣe inú dídùn sí ìpẹ̀gàn tó? Àwọn aláìgbọ́n kórìíra ìmọ̀? Bí ẹ bá ti gbọ́ ìbáwí ì mi ni, Ǹ bá ti tú ohun tí ó wà nínú ọkàn mi jáde fún yín kí n sì fi inú mi hàn sí i yín.