Àwọn obìnrin kan wà níbẹ̀ pẹ̀lú, tí wọ́n ń wò ó láti òkèèrè. Maria Magdalene wà lára àwọn obìnrin náà, àti Maria ìyá Jakọbu kékeré àti ti Jose, àti Salome. Àwọn wọ̀nyí, nígbà tí ó wà ní Galili máa ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, wọ́n a sì máa ṣe ìránṣẹ́ fún un àti ọ̀pọ̀ obìnrin mìíràn tí wọ́n sì bá a gòkè wá sí Jerusalẹmu. Ọjọ́ yìí jẹ́ ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́ (èyí tí ṣe, ọjọ́ tó ṣáájú ọjọ́ ìsinmi). Nígbà tí ilẹ̀ ọjọ́ náà sì ṣú, Josẹfu ará Arimatea wá, ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn ọmọ ìgbìmọ̀, ẹni tí ń retí ìjọba Ọlọ́run, ó fi ìgboyà lọ sí iwájú Pilatu láti tọrọ òkú Jesu. Ẹnu ya Pilatu láti gbọ́ pé Jesu ti kú. Nítorí náà ó pe balógun ọ̀rún, ó sì bí i léèrè bóyá Jesu ti kú nítòótọ́. Nígbà tí balógun ọ̀rún náà sì fún Pilatu ni ìdánilójú pé Jesu ti kú, Pilatu jọ̀wọ́ òkú rẹ̀ fún Josẹfu. Josẹfu sì ti ra aṣọ ọ̀gbọ̀ wá. Ó sọ òkú Jesu kalẹ̀: ó sì fi aṣọ ọ̀gbọ̀ náà dì í. Ó sì tẹ́ ẹ sí inú ibojì, tí wọ́n gbẹ́ sí ara àpáta. Ó wá yí òkúta dí ẹnu ibojì náà. Maria Magdalene àti Maria ìyá Jose ń wò ó bi Josẹfu ti n tẹ́ Jesu sí ibojì.
Kà Marku 15
Feti si Marku 15
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Marku 15:40-47
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò