Marku 15:22-32

Marku 15:22-32 YCB

Wọ́n sì mú Jesu wá sí Gọlgọta, (èyí tí ìtumọ̀ rẹ̀ ń jẹ́ Ibi Agbárí) Wọ́n sì fi (myrri) wáìnì tí a dàpọ̀ mọ́ òjìá fún un mu, ṣùgbọ́n òun kò gbà á. Wọ́n sì kàn án mọ́ àgbélébùú. Wọ́n sì pín aṣọ rẹ̀ láàrín ara wọn, wọ́n dìbò lórí àwọn aṣọ náà ni kí wọn bá à lè mọ èyí tí yóò jẹ́ ti olúkúlùkù. Ní wákàtí kẹta ọjọ́ ni wọ́n kàn án mọ́ àgbélébùú. Àkọlé ìfisùn tí wọ́n kọ sókè orí rẹ̀ ni: ọba àwọn júù. Wọ́n sì kan àwọn olè méjì mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú rẹ̀, ọ̀kan lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀, èkejì lọ́wọ́ òsì rẹ̀. Eléyìí mú àsọtẹ́lẹ̀ ìwé Mímọ́ ṣẹ wí pé, “Wọ́n kà á pọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn búburú.” Àwọn tí ń kọjá lọ sì ń fi ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n ń mi orí wọn pẹ̀lú, wọ́n sì ké pé, “Háà! Ìwọ tí yóò wó tẹmpili tí yóò sì tún un kọ́ láàrín ọjọ́ mẹ́ta, sọ̀kalẹ̀ láti orí àgbélébùú wá, kí o sì gba ara rẹ là!” Bákan náà ni àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin fi í ṣẹ̀sín láàrín ara wọn, wọ́n wí pé, “Ó gba àwọn ẹlòmíràn là ṣùgbọ́n, ara rẹ̀ ni kò lè gbàlà. Jẹ́ kí Kristi, ọba Israẹli, sọ̀kalẹ̀ láti orí igi àgbélébùú wá nísinsin yìí kí àwa kí ó lè rí i, kí àwa kí ó sì lè gbàgbọ́.” Bákan náà, àwọn ti a kàn mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú rẹ̀ sì ń kẹ́gàn rẹ̀.

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ