Marku 11:27-33

Marku 11:27-33 YCB

Lẹ́yìn èyí, wọ́n tún padà sí Jerusalẹmu. Bí Jesu ti ń rìn kiri ni tẹmpili, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin pẹ̀lú àwọn àgbàgbà Júù wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Wọ́n béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Àṣẹ wo ni ó fi ń ṣe nǹkan yìí? Ta ni ó sì fún ọ ni àṣẹ yìí láti máa ṣe nǹkan wọ̀nyí?” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Èmi yóò bi yín léèrè ọ̀rọ̀ kan, kí ẹ sì dá mi lóhùn, èmi yóò sọ fún yín àṣẹ tí èmi fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí.” Ìtẹ̀bọmi Johanu láti ọ̀run wa ni, tàbí láti ọ̀dọ̀ ènìyàn? “Ẹ dá mi lóhùn!” Wọ́n bá ara wọn jíròrò pé: “Bí a bá wí pé láti ọ̀run wá ni, òun ó wí pé, ‘nígbà tí ẹ mọ̀ bẹ́ẹ̀, èéṣe tí ẹ kò fi gbà à gbọ́?’ Ṣùgbọ́n bí a bá wí pé, Láti ọ̀dọ̀ ènìyàn, wọ́n bẹ̀rù àwọn ènìyàn, nítorí pé gbogbo ènìyàn ló gbàgbọ́ pé wòlíì gidi ni Johanu.” Nítorí náà, Wọ́n kọjú sí Jesu wọn sì dáhùn pé, “Àwa kò mọ̀.” Nígbà náà ni Jesu wí pé, “Níwọ́n ìgbà tí ẹ kò lè dáhùn ìbéèrè mi, Èmi náà kì yóò sọ fún yín àṣẹ tí mo fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí.”

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ