Marku 11:12-26

Marku 11:12-26 YCB

Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, bí wọ́n ti kúrò ní Betani, ebi ń pa Jesu. Ó rí igi ọ̀pọ̀tọ́ kan lọ́ọ̀ọ́kán tí ewé kún orí rẹ̀. Nígbà náà, ó lọ sí ìdí rẹ̀ láti wò ó bóyá ó léso tàbí kò léso. Nígbà tí ó dé ibẹ̀, ewé lásán ni ó rí, kò rí èso lórí rẹ̀. Nítorí pé àkókò náà kì í ṣe àkókò tí igi ọ̀pọ̀tọ́ máa ń so. Lẹ́yìn náà, Jesu pàṣẹ fún igi náà pé, “Kí ẹnikẹ́ni má ṣe jẹ èso lórí rẹ mọ́ títí láé.” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ gbọ́ nígbà tí ó wí bẹ́ẹ̀. Nígbà ti wọ́n padà sí Jerusalẹmu, ó wọ inú tẹmpili. Ó bẹ̀rẹ̀ sí nílé àwọn oníṣòwò àti àwọn oníbàárà wọn síta. Ó ti tábìlì àwọn tí ń pààrọ̀ owó nínú tẹmpili ṣubú. Bákan náà ni ó ti ìjókòó àwọn tí ń ta ẹyẹlé lulẹ̀. Kò sì gba ẹnikẹ́ni láààyè láti gbé ẹrù ọjà títà gba inú tẹmpili wọlé. Gẹ́gẹ́ bí ó ti kọ́ wọn, ó wí pé, “Ṣé a kò ti kọ ọ́ pé: ‘Ilé àdúrà ni a o máa pe ilé mi, ní gbogbo orílẹ̀-èdè?’ Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti sọ ọ́ di ibùgbé àwọn ọlọ́ṣà.” Nígbà tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin gbọ́ ohun tí ó ti ṣe, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ń gbà èrò bí wọn yóò ti ṣe pa á. Wọ́n bẹ̀rù rògbòdìyàn tí yóò bẹ́ sílẹ̀, nítorí tí àwọn ènìyàn ní ìgbóná ọkàn sí ẹ̀kọ́ rẹ̀. Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà, bí ìṣe wọn, Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ jáde kúrò ní ìlú Jerusalẹmu. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, bí wọ́n ti ń kọjá lọ, wọ́n rí igi ọ̀pọ̀tọ́ tí Jesu fi bú. Wọ́n rí i pé ó ti gbẹ tigbòǹgbò tigbòǹgbò. Peteru rántí pé Jesu ti bá igi náà wí. Nígbà náà ni ó sọ fún Jesu pé, “Rabbi, Wò ó! Igi ọ̀pọ̀tọ́ tí ìwọ fi bú ti gbẹ!” Jesu sì dáhùn pé, “Ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, Lóòótọ́ ni mò wí fún un yín, bí ẹnikẹ́ni bá wí fún òkè ‘ṣídìí, gbé ara rẹ sọ sínú Òkun’ ti kò sì ṣe iyèméjì nínú ọkàn rẹ̀ ṣùgbọ́n tí ó gbàgbọ́ pé ohun tí òun wí yóò ṣẹ, yóò rí bẹ́ẹ̀ fún un. Torí náà, mo wí fún yín ohunkóhun tí ẹ bá béèrè fún nínú àdúrà, ẹ ní ìgbàgbọ́ pé, ó tí tẹ̀ yín lọ́wọ́, yóò sì jẹ́ tiyín. Nígbà tí ẹ bá ń gbàdúrà, ẹ kọ́kọ́ dáríjì, bí ẹ̀yin bá ní ohunkóhun sí ẹnikẹ́ni, kí baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run bá à le dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tiyín náà jì yín. Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá dáríjì, Baba yín ti ń bẹ ni ọ̀run kí yóò dárí ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín.”