Matiu 5:23-25

Matiu 5:23-25 YCB

“Nítorí náà, nígbà tí ìwọ bá ń mú ẹ̀bùn rẹ wá síwájú pẹpẹ, bí ìwọ bá sì rántí níbẹ̀ pé arákùnrin rẹ̀ ni ohùn kan nínú sí ọ. Fi ẹ̀bùn rẹ sílẹ̀ níwájú pẹpẹ. Ìwọ kọ́kọ́ lọ ṣe ìlàjà láàrín ìwọ àti arákùnrin rẹ̀ na. Lẹ́yìn náà, wá kí ó sì fi ẹ̀bùn rẹ sílẹ̀. “Bá ọ̀tá rẹ làjà kánkán, ẹni tí ó ń gbé ọ lọ sílé ẹjọ́. Ṣe é nígbà ti ó wà ní ọ̀nà pẹ̀lú rẹ, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ yóò fà ọ́ lé onídàájọ́ lọ́wọ́, onídàájọ́ yóò sí fá ọ lé àwọn ẹ̀ṣọ́ lọ́wọ́, wọ́n a sì sọ ọ́ sínú túbú.

Àwọn fídíò fún Matiu 5:23-25