Ẹnìkan sì wá ó bí Jesu pé, “Olùkọ́, ohun rere kí ni èmi yóò ṣe, kí èmi kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun?” Jesu dá a lóhùn pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ń béèrè nípa ohun rere lọ́wọ́ mi. Ẹni kan ṣoṣo ni ó wà tí í ṣe Ẹni rere. Bí ìwọ bá fẹ́ dé ibi ìyè, pa àwọn òfin mọ́.” Ọkùnrin náà béèrè pé, “Àwọn wo ni òfin wọ̀nyí?” Jesu dáhùn pé, “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn; Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà; Ìwọ kò gbọdọ̀ jalè; Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́rìí èké’, bọ̀wọ̀ fún baba àti ìyá rẹ. ‘Kí o sì fẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.’ ” Ọmọdékùnrin náà tún wí pé, “Gbogbo òfin wọ̀nyí ni èmi ti ń pamọ́, kí ni nǹkan mìíràn tí èmi ní láti ṣe?” Jesu wí fún un pé, “Bí ìwọ bá fẹ́ di ẹni pípé, lọ ta ohun gbogbo tí ìwọ ní, kí o sì fi owó rẹ̀ tọrẹ fún àwọn aláìní. Ìwọ yóò ní ọrọ̀ ńlá ní ọ̀run. Lẹ́yìn náà, wá láti máa tọ̀ mi lẹ́yìn.”
Kà Matiu 19
Feti si Matiu 19
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Matiu 19:16-21
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò