“Nítorí náà, ìjọba ọ̀run dàbí ọba kan tí ó fẹ́ ṣe ìṣirò pẹ̀lú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀. Bí ó ti ń ṣe èyí, a mú ajigbèsè kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀ tí ó jẹ ẹ́ ní ẹgbàárùn-ún (10,000) tálẹ́ǹtì. Nígbà tí kò tì í ní agbára láti san án, nígbà náà ni olúwa rẹ̀ pàṣẹ pé kí a ta òun àti ìyàwó àti àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó ní láti fi san gbèsè náà. “Nígbà náà ni ọmọ ọ̀dọ̀ náà wólẹ̀ lórí eékún níwájú rẹ. ‘Ó bẹ̀bẹ̀ pé, mú sùúrù fún mi, èmi yóò sì san gbogbo rẹ̀ fún ọ.’ Nígbà náà, ni olúwa ọmọ ọ̀dọ̀ náà sì ṣàánú fún un. Ó tú u sílẹ̀, ó sì fi gbèsè náà jì í.
Kà Matiu 18
Feti si Matiu 18
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Matiu 18:23-27
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò