Matiu 14:22-33

Matiu 14:22-33 YCB

Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ lẹ́yìn èyí, Jesu wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kí wọ́n bọ sínú ọkọ̀ wọn, àti kí wọ́n máa kọjá lọ ṣáájú rẹ̀ sí òdìkejì. Òun náà dúró lẹ́yìn láti tú àwọn ènìyàn ká lọ sí ilé wọn Lẹ́yìn tí ó tú ìjọ ènìyàn ká tán, ó gun orí òkè lọ fúnrarẹ̀ láti lọ gba àdúrà. Nígbà tí ilẹ̀ ṣú, òun wà nìkan níbẹ̀, ní àkókò yìí ọkọ̀ ojú omi náà ti rin jìnnà sí etí bèbè Òkun, tí ìjì omi ń tì í síwá sẹ́yìn, nítorí ìjì ṣe ọwọ́ òdì sí wọn. Ní déédé ago mẹ́rin òwúrọ̀, Jesu tọ̀ wọ́n wá, ó ń rìn lórí omi. Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rí i tí ó ń rìn lójú omi, ẹ̀rù ba wọn gidigidi, wọ́n rò pé “iwin ni” wọ́n kígbe tìbẹ̀rù tìbẹ̀rù. Lójúkan náà, Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ mú ọkàn le! Èmi ni ẹ má ṣe bẹ̀rù.” Peteru sì ké sí i pé, “Olúwa, bí ó bá jẹ́ pé ìwọ ni nítòótọ́, sọ pé kí n tọ̀ ọ́ wà lórí omi.” Jesu dá a lóhùn pé, “Ó dára, máa bọ̀ wá.” Nígbà náà ni Peteru sọ̀kalẹ̀ láti inú ọkọ̀. Ó ń rìn lórí omi lọ sí ìhà ọ̀dọ̀ Jesu. Nígbà tí ó rí afẹ́fẹ́ líle, ẹ̀rù bà á, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í rì. Ó kígbe lóhùn rara pé, “Gbà mí, Olúwa.” Lójúkan náà, Jesu na ọwọ́ rẹ̀, ó dìímú, ó sì gbà á. Ó sì wí fún un pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ṣiyèméjì ìwọ onígbàgbọ́ kékeré?” Àti pé, nígbà ti wọ́n sì gòkè sínú ọkọ̀, ìjì náà sì dúró jẹ́ẹ́. Nígbà náà ni àwọn to wà nínú ọkọ̀ náà foríbalẹ̀ fún un wọ́n wí pé, “Nítòótọ́ ọmọ Ọlọ́run ni ìwọ í ṣe.”