Jesu sì fi agbára Ẹ̀mí padà wá sí Galili: òkìkí rẹ̀ sì kàn kálẹ̀ ní gbogbo agbègbè tí ó yí i ká. Ó sì ń kọ́ni nínú Sinagọgu wọn; a ń yìn ín lógo láti ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn ènìyàn wá. Ó sì wá sí Nasareti, níbi tí a gbé ti tọ́ ọ dàgbà: bí ìṣe rẹ̀ ti rí, ó sì wọ inú Sinagọgu lọ ní ọjọ́ ìsinmi, ó sì dìde láti kàwé. A sì fi ìwé wòlíì Isaiah fún un. Nígbà tí ó sì ṣí ìwé náà, ó rí ibi tí a gbé kọ ọ́ pé: “Ẹ̀mí Olúwa ń bẹ lára mi, Nítorí tí ó fi ààmì òróró yàn mí láti wàásù ìhìnrere fún àwọn òtòṣì. Ó ti rán mi wá láti wàásù ìdásílẹ̀ fún àwọn ìgbèkùn, àti ìmúnríran fún àwọn afọ́jú, àti láti jọ̀wọ́ àwọn tí a pa lára lọ́wọ́, láti kéde ọdún ojúrere Olúwa.” Ó sì pa ìwé náà dé, ó fi í fún ìránṣẹ́, ó sì jókòó. Gbogbo àwọn tí ó ń bẹ nínú Sinagọgu sì tẹjúmọ́ ọn. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wí fún wọn pé, “Lónìí ìwé mímọ́ yìí ṣẹ ní etí yín.” Gbogbo wọn sì jẹ́rìí rẹ̀, háà sì ṣe wọ́n sí ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ tí ń jáde ní ẹnu rẹ̀, wọ́n sì wí pé, “Ọmọ Josẹfu kọ́ yìí?”
Kà Luku 4
Feti si Luku 4
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Luku 4:14-22
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò