Luku 2:41-52

Luku 2:41-52 YCB

Àwọn òbí rẹ̀ a sì máa lọ sí Jerusalẹmu ní ọdọọdún sí àjọ ìrékọjá. Nígbà tí ó sì di ọmọ ọdún méjìlá, wọ́n gòkè lọ sí Jerusalẹmu gẹ́gẹ́ bí ìṣe àjọ náà. Nígbà tí ọjọ́ wọn sì pé bí wọ́n ti ń padà bọ̀, ọmọ náà, Jesu dúró lẹ́yìn ní Jerusalẹmu; Josẹfu àti ìyá rẹ̀ kò mọ̀. Ṣùgbọ́n wọ́n ṣe bí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ èrò, wọ́n rin ìrìn ọjọ́ kan; wọ́n wá a kiri nínú àwọn ará àti àwọn ojúlùmọ̀ wọn. Nígbà tí wọn kò sì rí i, wọ́n padà sí Jerusalẹmu, wọ́n ń wá a kiri. Ó sì ṣe, lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta wọ́n rí i nínú tẹmpili ó jókòó ní àárín àwọn olùkọ́ni, ó ń gbọ́ tiwọn, ó sì ń bi wọ́n léèrè. Ẹnu sì ya gbogbo àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ fún òye àti ìdáhùn rẹ̀. Nígbà tí wọ́n sì rí i, háà ṣe wọ́n: ìyá rẹ̀ sì bi í pé, “Ọmọ, èéṣe tí ìwọ fi ṣe wá bẹ́ẹ̀? Sá wò ó, baba rẹ̀ àti èmi ti ń fi ìbànújẹ́ wá ọ kiri.” Ó sì dáhùn wí fún wọn pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń wá mi kiri, ẹ̀yin kò mọ̀ pé èmi kò lè ṣàìmá wà níbi iṣẹ́ Baba mi?” Ọ̀rọ̀ tí o sọ kò sì yé wọn. Ó sì bá wọn sọ̀kalẹ̀ lọ sí Nasareti, sì fi ara balẹ̀ fún wọn: ṣùgbọ́n ìyá rẹ̀ pa gbogbo nǹkan wọ̀nyí mọ́ nínú ọkàn rẹ̀. Jesu sì ń pọ̀ ní ọgbọ́n, sì ń dàgbà, ó sì wà ní ojúrere ní ọ̀dọ̀ Ọlọ́run àti ènìyàn.