Luku 17:1-19

Luku 17:1-19 YCB

Ó sì wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Kò le ṣe kí ohun ìkọ̀sẹ̀ máa wa: ṣùgbọ́n ègbé ni fún ẹni tí ó ti ipasẹ̀ rẹ̀ dé. Ìbá sàn fún un kí a so ọlọ mọ́ ọn ní ọrùn, kí a sì gbé e jù sínú Òkun, ju kí ó mú ọ̀kan nínú àwọn kékeré wọ̀nyí kọsẹ̀. Ẹ máa kíyèsára yín. “Bí arákùnrin rẹ bá ṣẹ̀, bá a wí; bí ó bá sì ronúpìwàdà, dáríjì ín. Bí ó bá sì ṣẹ̀ ọ́ ní igba méje ní òòjọ́, tí ó padà tọ̀ ọ́ wá ní ìgbà méje ní òòjọ́ pé, ‘Mo ronúpìwàdà,’ dáríjì ín.” Àwọn aposteli sì wí fún Olúwa pé, “Bù sí ìgbàgbọ́ wa.” Olúwa sì wí pé, “Bí ẹ̀yin bá ní ìgbàgbọ́ bí hóró irúgbìn musitadi, ẹ̀yin yóò lè wí fún igi sikamine yìí pé, ‘di fi fà á tu, kí a sì gbìn ọ́ sínú Òkun,’ yóò sì gbọ́ tiyín. “Ṣùgbọ́n ta ni nínú yín, tí ó ní ọmọ ọ̀dọ̀, tí ó ń tulẹ̀, tàbí tí ó ń bọ́ ẹran, tí yóò wí fún un lójúkan náà tí ó bá ti oko dé pé, ‘Lọ í jókòó láti jẹun’? Tí kì yóò kúkú wí fún un pé, ‘Pèsè ohun tí èmi yóò jẹ, sì di àmùrè, kí ìwọ kí ó máa ṣe ìránṣẹ́ fún mi, títí èmi ó fi jẹ kí èmi ó sì mu tán; lẹ́yìn náà ni ìwọ ó sì jẹ, tí ìwọ ó sì mu’? Òun ó ha máa dá ọpẹ́ lọ́wọ́ ọmọ ọ̀dọ̀ náà, nítorí ó ṣe ohun tí a pàṣẹ fún un bí? Èmi kò rò bẹ́ẹ̀. Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin pẹ̀lú, nígbà tí ẹ bá ti ṣe ohun gbogbo tí a pàṣẹ fún yín tán, ẹ wí pé, ‘Aláìlérè ọmọ ọ̀dọ̀ ni wá: èyí tí í ṣe iṣẹ́ wa láti ṣe, ní àwa ti ṣe.’ ” Ó sì ṣe, bí ó ti ń lọ sí Jerusalẹmu, ó kọjá láàrín Samaria Galili. Bí ó sì ti ń wọ inú ìletò kan lọ, àwọn ọkùnrin adẹ́tẹ̀ mẹ́wàá pàdé rẹ̀, wọ́n dúró ní òkèrè: Wọ́n sì kígbe sókè, wí pé, “Jesu, Olùkọ́, ṣàánú fún wa.” Nígbà tí ó rí wọn, ó wí fún wọn pé, “Ẹ lọ í fi ara yín hàn fún àwọn àlùfáà.” Ó sì ṣe, bí wọ́n ti ń lọ, wọ́n sì di mímọ́. Nígbà tí ọ̀kan nínú wọn rí i pé a mú Òun láradá ó padà, ó sì fi ohùn rara yin Ọlọ́run lógo. Ó sì wólẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀, ó ń dúpẹ́ ní ọwọ́ rẹ̀: ará Samaria ni òun í ṣe. Jesu sì dáhùn wí pé, “Àwọn mẹ́wàá kí a sọ di mímọ́? Àwọn mẹ́sàn-án ìyókù ha dà? A kò rí ẹnìkan tí ó padà wá fi ògo fún Ọlọ́run, bí kò ṣe àlejò yìí?” Ó sì wí fún un pé, “Dìde, kí o sì máa lọ: ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ láradá.”