Luku 11:29-54

Luku 11:29-54 YCB

Nígbà tí ìjọ ènìyàn sì ṣùjọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí wí pé, “Ìran búburú ni èyí: wọ́n ń wá ààmì; a kì yóò sì fi ààmì kan fún un bí kò ṣe ààmì Jona wòlíì! Nítorí bí Jona ti jẹ́ ààmì fún àwọn ará Ninefe, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni Ọmọ ènìyàn yóò ṣe jẹ́ ààmì fún ìran yìí. Ọbabìnrin gúúsù yóò dìde ní ọjọ́ ìdájọ́ pẹ̀lú àwọn ènìyàn ìran yìí, yóò sì dá wọn lẹ́bi: nítorí tí ó ti ìhà ìpẹ̀kun ayé wá láti gbọ́ ọgbọ́n Solomoni: sì kíyèsi i, ẹni tí ó pọ̀jù Solomoni lọ ń bẹ níhìn-ín yìí. Àwọn ará Ninefe yóò dìde ní ọjọ́ ìdájọ́ pẹ̀lú ìran yìí, wọn ó sì dá a lẹ́bi: nítorí tí wọn ronúpìwàdà nípa ìwàásù Jona; sì kíyèsi i, ẹni tí ó pọ̀jù Jona lọ ń bẹ níhìn-ín yìí. “Kò sí ẹnìkan, nígbà tí ó bá tan fìtílà tan, tí gbé e sí ìkọ̀kọ̀, tàbí sábẹ́ òṣùwọ̀n, bí kò ṣe sórí ọ̀pá fìtílà, kí àwọn tí ń wọlé ba à lè máa rí ìmọ́lẹ̀. Ojú ni fìtílà ara: bí ojú rẹ bá mọ́lẹ̀ kedere, gbogbo ara rẹ a mọ́lẹ̀; ṣùgbọ́n bí ojú rẹ bá ṣókùnkùn, ara rẹ pẹ̀lú a kún fún òkùnkùn. Nítorí náà kíyèsi i, kí ìmọ́lẹ̀ tí ń bẹ nínú rẹ má ṣe di òkùnkùn. Ǹjẹ́ bí gbogbo ara rẹ bá kún fún ìmọ́lẹ̀, tí kò ní apá kan tí ó ṣókùnkùn, gbogbo rẹ̀ ni yóò ní ìmọ́lẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí fìtílà bá fi ìtànṣán rẹ̀ fún ọ ní ìmọ́lẹ̀.” Bí ó sì ti ń wí, Farisi kan bẹ̀ ẹ́ kí ó bá òun jẹun: ó sì wọlé, ó jókòó láti jẹun. Nígbà tí Farisi náà sì rí i, ẹnu yà á nítorí tí kò kọ́kọ́ wẹ ọwọ́ kí ó tó jẹun. Olúwa sì wí fún un pé, “Ẹ̀yin Farisi a máa ń fọ òde ago àti àwopọ̀kọ́: ṣùgbọ́n, inú yín kún fún ìwà búburú àti ìrẹ́jẹ. Ẹ̀yin aṣiwèrè, ẹni tí ó ṣe èyí tí ń bẹ lóde, òun kò ha ṣe èyí tí ń bẹ nínú pẹ̀lú? Nípa ohun ti inú yin, ki ẹ̀yin kúkú máa ṣe ìtọrẹ àánú nínú ohun tí ẹ̀yin ní, sì kíyèsi i, ohun gbogbo ni ó di mímọ́ fún yín. “Ṣùgbọ́n ègbé ni fún yín, ẹ̀yin Farisi, nítorí tí ẹ̀yin a máa san ìdámẹ́wàá minti àti irúgbìn, àti gbogbo ewébẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kọ ìdájọ́ àti ìfẹ́ Ọlọ́run: wọ̀nyí jẹ́ ohun tí ẹ gbọdọ̀ ṣe, láìsí fi àwọn ìyókù sílẹ̀ láìṣe. “Ègbé ni fún yín, ẹ̀yin Farisi, àgàbàgebè! Nítorí tí ẹ̀yin fẹ́ ipò ọlá nínú Sinagọgu, àti ìkíni ní ọjà. “Ègbé ni fún un yín, (ẹ̀yin akọ̀wé àti ẹ̀yin Farisi àgàbàgebè) nítorí ẹ̀yin dàbí ibojì tí kò farahàn, tí àwọn ènìyàn sì ń rìn lórí rẹ̀ láìmọ̀.” Nígbà náà ni ọ̀kan nínú àwọn amòfin dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Olùkọ́, nínú èyí tí ìwọ ń wí yìí ìwọ ń gan àwa pẹ̀lú.” Ó sì wí pé, “Ègbé ni fún ẹ̀yin amòfin pẹ̀lú, nítorí tí ẹ̀yin di ẹrù tí ó wúwo láti rù lé ènìyàn lórí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin tìkára yín kò jẹ́ fi ìka yín kan ẹrù náà. “Ègbé ni fún yín, nítorí tí ẹ̀yin kọ́ ibojì àwọn wòlíì, tí àwọn baba yín pa. Ǹjẹ́ ẹ̀yin jẹ́ ẹlẹ́rìí, ẹ sì ní inú dídùn sí iṣẹ́ àwọn baba yín, nítorí tí wọn pa wọ́n, ẹ̀yin sì kọ́ ibojì wọn. Nítorí èyí ni ọgbọ́n Ọlọ́run sì ṣe wí pé, ‘Èmi ni ó rán àwọn wòlíì àti àwọn aposteli sí wọn, wọn ó sì ṣe inúnibíni sí wọn.’ Kí a lè béèrè ẹ̀jẹ̀ àwọn wòlíì gbogbo, tí a ti ta sílẹ̀ láti ìgbà ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé wá, lọ́wọ́ ìran yìí; láti ẹ̀jẹ̀ Abeli wá, títí ó sì fi dé ẹ̀jẹ̀ Sekariah, tí ó ṣègbé láàrín pẹpẹ àti tẹmpili: lóòótọ́ ni mo wí fún yín ìran yìí ni yóò ru gbogbo ẹ̀bi àwọn nǹkan wọ̀nyí. “Ègbé ni fún yín, ẹ̀yin amòfin, nítorí tí ẹ̀yin ti mú kọ́kọ́rọ́ ìmọ̀ kúrò; ẹ̀yin tìkára yín kò wọlé, àwọn tí sì ń wọlé, ni ẹ̀yin ń dí lọ́wọ́.” Bí ó ti ń lọ kúrò níbẹ̀, àwọn akọ̀wé àti àwọn Farisi bẹ̀rẹ̀ sí bi í lọ́rọ̀ gidigidi, wọ́n sì ń yọ ọ́ lẹ́nu láti wí nǹkan púpọ̀. Wọ́n ń ṣọ́ ọ, wọ́n ń wá ọ̀nà láti rí nǹkan gbámú lẹ́nu kí wọn bá à lè fi ẹ̀sùn kàn án.