Joẹli 2:18-32

Joẹli 2:18-32 YCB

Nígbà náà ní OLúWA yóò jowú fún ilẹ̀ rẹ̀, yóò sì káàánú fún ènìyàn rẹ̀. Nítòótọ́, OLúWA yóò dá wọn lóhùn: “Yóò sì wí fun àwọn ènìyàn rẹ̀ pé, Wò ó èmi yóò rán ọkà, àti ọtí wáìnì tuntun, àti òróró sí i yín, a ó sì fi wọn tẹ́ yín lọ́rùn: èmi kì yóò sì fi yín ṣe ẹ̀gàn mọ́ láàrín àwọn aláìkọlà. “Ṣùgbọ́n èmi yóò lé ogun àríwá jìnnà réré kúrò lọ́dọ̀ yín, èmi yóò sì lé e lọ sí ilẹ̀ tí ó ṣá, tí ó sì di ahoro, pẹ̀lú ojú rẹ̀ sí Òkun ìlà-oòrùn, àti ẹ̀yìn rẹ̀ sí ìwọ̀-oòrùn Òkun. Òórùn rẹ̀ yóò sì gòkè, òórùn búburú rẹ̀ yóò sì gòkè.” Nítòótọ́ ó ti ṣe ohun ńlá. Má bẹ̀rù, ìwọ ilẹ̀; jẹ́ kí inú rẹ̀ dùn kí o sì yọ̀, nítorí OLúWA ti ṣe ohun ńlá, Ẹ má bẹ̀rù, ẹranko igbó, nítorí pápá oko aginjù ń rú, nítorí igi ń so èso rẹ̀, igi ọ̀pọ̀tọ́ àti àjàrà ń so èso ọ̀rọ̀ wọn. Ẹ jẹ́ kí inú yín dùn, ẹ̀yin ọmọ Sioni, ẹ sì yọ̀ nínú OLúWA Ọlọ́run yín, nítorí ó ti fi àkọ́rọ̀ òjò fún yín bí ó ti tọ́, Òun ti mú kí òjò rọ̀ sílẹ̀ fún un yín, àkọ́rọ̀ àti àrọ̀kúrò òjò ní oṣù kìn-ín-ní. Àwọn ilẹ̀ ìpakà yóò kún fún ọkà; àti ọpọ́n wọn nì yóò sàn jáde pẹ̀lú ọtí wáìnì tuntun àti òróró. “Èmi yóò sì mú ọdún wọ̀nyí ti eṣú jẹ run padà fún un yín. Èyí tí eṣú agénijẹ àti eṣú jewéjewé ọwọ́ eṣú agénijẹ àti kòkòrò ajẹnirun mìíràn ti fi jẹ àwọn ogun ńlá mi tí mo rán sí àárín yín. Ẹ̀yin yóò ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ láti jẹ, títí ẹ̀yin yóò fi yó ẹ ó sì yín orúkọ OLúWA Ọlọ́run yín, ẹni tí ó fi ìyanu bá yín lò; ojú kì yóò sì ti àwọn ènìyàn mi láéláé. Ẹ̀yin yóò sì mọ̀ pé, èmi wà láàrín Israẹli, àti pé; Èmi ni OLúWA Ọlọ́run yín, àti pé kò sí ẹlòmíràn: Ojú kì yóò sì ti àwọn ènìyàn mí láéláé. OLúWA “Yóò sì ṣe níkẹyìn ọjọ́, èmi yóò tú nínú Ẹ̀mí mí sí ara ènìyàn gbogbo; àwọn ọmọ yín ọkùnrin àti àwọn ọmọ yín obìnrin yóò máa sọtẹ́lẹ̀, àwọn arúgbó yín yóò máa lá àlá, àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yín yóò máa ríran. Àti pẹ̀lú sí ara àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ ọkùnrin, àti sí ara àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ obìnrin, ní èmi yóò tú ẹ̀mí mí jáde ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì. Èmi yóò sì fi iṣẹ́ ìyanu hàn ní ọrun àti ní ayé, ẹ̀jẹ̀ àti iná, àti ọ̀wọ́n èéfín. A á sọ oòrùn di òkùnkùn, àti òṣùpá di ẹ̀jẹ̀, kí ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ ẹ̀rù OLúWA tó dé. Yóò sí ṣe, ẹnikẹ́ni tí ó ba ké pè orúkọ OLúWA ní a ó gbàlà: nítorí ní òkè Sioni àti ní Jerusalẹmu ní ìgbàlà yóò gbé wà, bí OLúWA ti wí, àti nínú àwọn ìyókù tí OLúWA yóò pè.