Johanu 6:40-71

Johanu 6:40-71 YCB

Èyí sì ni ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi, pé ẹnikẹ́ni tí ó bá wo ọmọ, tí ó bá sì gbà á gbọ́, kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun: Èmi ó sì jí i dìde níkẹyìn ọjọ́.” Nígbà náà ni àwọn Júù ń kùn sí i, nítorí tí ó wí pé, “Èmi ni oúnjẹ tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá.” Wọ́n sì wí pé, “Jesu ha kọ́ èyí, ọmọ Josẹfu, baba àti ìyá ẹni tí àwa mọ̀? Báwo ni ó ṣe wí pé, ‘Èmi ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá’?” Nítorí náà Jesu dáhùn, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe kùn láàrín yín! Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè wá sọ́dọ̀ mi, bí kò ṣe pé Baba tí ó rán mi fà á: Èmi ó sì jí i dìde níkẹyìn ọjọ́. A sá à ti kọ ọ́ nínú ìwé àwọn wòlíì pé, ‘A ó sì kọ́ gbogbo wọn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá,’ nítorí náà ẹnikẹ́ni tí ó bá ti gbọ́, tí a sì ti ọ̀dọ̀ Baba kọ́, òun ni ó ń tọ̀ mí wá. Kì í ṣe pé ẹnìkan ti rí Baba bí kò ṣe ẹni tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, òun ni ó ti rí Baba. Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, ó ní ìyè àìnípẹ̀kun. Èmi ni oúnjẹ ìyè. Àwọn baba yín jẹ manna ní aginjù, wọ́n sì kú. Èyí ni oúnjẹ tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, kí ènìyàn lè máa jẹ nínú rẹ̀ kí ó má sì kú. Èmi ni oúnjẹ ìyè náà tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá: bí ẹnikẹ́ni bá jẹ nínú oúnjẹ yìí, yóò yè títí láéláé: oúnjẹ náà tí èmi ó sì fi fún ni fún ìyè aráyé ni ara mi.” Nítorí náà ni àwọn Júù ṣe ń bá ara wọn jiyàn, pé, “Ọkùnrin yìí yóò ti ṣe lè fi ara rẹ̀ fún wa láti jẹ?” Nígbà náà ni Jesu wí fún wọn pé, “Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, bí kò ṣe pé ẹ̀yin bá jẹ ara ọmọ ènìyàn, kí ẹ sì mu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ẹ̀yin kò ní ìyè nínú yin. Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ara mi, tí ó bá sì mu ẹ̀jẹ̀ mi, ó ní ìyè tí kò nípẹ̀kun; Èmi o sì jí i dìde níkẹyìn ọjọ́. Nítorí ara mi ni ohun jíjẹ nítòótọ́, àti ẹ̀jẹ̀ mi ni ohun mímu nítòótọ́. Ẹni tí ó bá jẹ ara mi, tí ó bá sì mu ẹ̀jẹ̀ mi, ó ń gbé inú mi, èmi sì ń gbé inú rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí Baba alààyè ti rán mi, tí èmi sì yè nípa Baba gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó jẹ mí, òun pẹ̀lú yóò yè nípa mi. Èyí sì ni oúnjẹ náà tí ó sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá: kì í ṣe bí àwọn baba yín ti jẹ manna, tí wọ́n sì kú: ẹni tí ó bá jẹ́ oúnjẹ yìí yóò yè láéláé.” Nǹkan wọ̀nyí ni ó sọ nínú Sinagọgu, bí ó ti ń kọ́ni ní Kapernaumu. Nítorí náà nígbà tí ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ gbọ́ èyí, wọ́n wí pé, “Ọ̀rọ̀ tí ó le ni èyí; ta ní lè gbọ́ ọ?” Nígbà tí Jesu sì mọ̀ nínú ara rẹ̀ pé àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń kùn sí ọ̀rọ̀ náà, ó wí fún wọn pé, “Èyí jẹ́ ìkọ̀sẹ̀ fún yín bí? Ǹjẹ́, bí ẹ̀yin bá sì rí i tí ọmọ ènìyàn ń gòkè lọ sí ibi tí ó gbé ti wà rí ńkọ́? Ẹ̀mí ní ń sọ ni di ààyè; ara kò ní èrè kan; ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí mo sọ fún yín, ẹ̀mí ni, ìyè sì ni pẹ̀lú. Ṣùgbọ́n àwọn kan wà nínú yín tí kò gbàgbọ́.” Nítorí Jesu mọ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ wá ẹni tí wọ́n jẹ́ tí kò gbàgbọ́, àti ẹni tí yóò fi òun hàn. Ó sì wí pé, “Nítorí náà ni mo ṣe wí fún yín pé, kò sí ẹni tí ó lè tọ̀ mí wá, bí kò ṣe pé a fi fún un láti ọ̀dọ̀ Baba mi wá.” Nítorí èyí ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ padà sẹ́yìn, wọn kò sì bá a rìn mọ́. Nítorí náà Jesu wí fún àwọn méjìlá pé, “Ẹ̀yin pẹ̀lú ń fẹ́ lọ bí?” Nígbà náà ni Simoni Peteru dá a lóhùn pé, “Olúwa, ọ̀dọ̀ ta ni àwa ó lọ? Ìwọ ni ó ni ọ̀rọ̀ ìyè àìnípẹ̀kun. Àwa sì ti gbàgbọ́, a sì mọ̀ pé ìwọ ni Kristi náà, Ọmọ Ọlọ́run alààyè.” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin méjìlá kọ́ ni mo yàn, ọ̀kan nínú yín kò ha sì ya èṣù?” (Ó ń sọ ti Judasi Iskariotu ọmọ Simoni ọ̀kan nínú àwọn méjìlá: nítorí pé òun ni ẹni tí yóò fi í hàn.)

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Johanu 6:40-71