Nígbà náà ni Jesu wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún yín, kì í ṣe Mose ni ó fi oúnjẹ fún yín láti ọ̀run wá; ṣùgbọ́n Baba mi ni ó fi oúnjẹ òtítọ́ náà fún yín láti ọ̀run wá. Nítorí pé oúnjẹ Ọlọ́run ni èyí tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, tí ó sì fi ìyè fún aráyé.”
Nígbà náà ni wọ́n wí fún un pé, “Olúwa, máa fún wa ní oúnjẹ yìí títí láé.”
Jesu wí fún wọn pé, “Èmi ni oúnjẹ ìyè: ẹnikẹ́ni tí ó bá tọ̀ mí wá, ebi kì yóò pa á; ẹni tí ó bá sì gbà mí gbọ́, òǹgbẹ kì yóò gbẹ ẹ́ mọ́ láé. Ṣùgbọ́n mo wí fún yín pé, Ẹ̀yin ti rí mi, ẹ kò sì gbàgbọ́. Gbogbo èyí tí Baba fi fún mi, yóò tọ̀ mí wá; ẹni tí ó bá sì tọ̀ mí wá, èmi kì yóò tà á nù, bí ó tí wù kó rí. Nítorí èmi sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá, kì í ṣe láti máa ṣe ìfẹ́ ti èmi fúnra mi, bí kò ṣe ìfẹ́ ti ẹni tí ó rán mi. Èyí sì ni ìfẹ́ Baba tí ó rán mi pé ohun gbogbo tí o fi fún mi, kí èmi má ṣe sọ ọ̀kan nù nínú wọn, ṣùgbọ́n kí èmi lè jí wọn dìde níkẹyìn ọjọ́. Èyí sì ni ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi, pé ẹnikẹ́ni tí ó bá wo ọmọ, tí ó bá sì gbà á gbọ́, kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun: Èmi ó sì jí i dìde níkẹyìn ọjọ́.”
Nígbà náà ni àwọn Júù ń kùn sí i, nítorí tí ó wí pé, “Èmi ni oúnjẹ tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá.” Wọ́n sì wí pé, “Jesu ha kọ́ èyí, ọmọ Josẹfu, baba àti ìyá ẹni tí àwa mọ̀? Báwo ni ó ṣe wí pé, ‘Èmi ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá’?”
Nítorí náà Jesu dáhùn, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe kùn láàrín yín! Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè wá sọ́dọ̀ mi, bí kò ṣe pé Baba tí ó rán mi fà á: Èmi ó sì jí i dìde níkẹyìn ọjọ́. A sá à ti kọ ọ́ nínú ìwé àwọn wòlíì pé, ‘A ó sì kọ́ gbogbo wọn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá,’ nítorí náà ẹnikẹ́ni tí ó bá ti gbọ́, tí a sì ti ọ̀dọ̀ Baba kọ́, òun ni ó ń tọ̀ mí wá. Kì í ṣe pé ẹnìkan ti rí Baba bí kò ṣe ẹni tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, òun ni ó ti rí Baba. Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, ó ní ìyè àìnípẹ̀kun. Èmi ni oúnjẹ ìyè. Àwọn baba yín jẹ manna ní aginjù, wọ́n sì kú. Èyí ni oúnjẹ tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, kí ènìyàn lè máa jẹ nínú rẹ̀ kí ó má sì kú. Èmi ni oúnjẹ ìyè náà tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá: bí ẹnikẹ́ni bá jẹ nínú oúnjẹ yìí, yóò yè títí láéláé: oúnjẹ náà tí èmi ó sì fi fún ni fún ìyè aráyé ni ara mi.”
Nítorí náà ni àwọn Júù ṣe ń bá ara wọn jiyàn, pé, “Ọkùnrin yìí yóò ti ṣe lè fi ara rẹ̀ fún wa láti jẹ?”
Nígbà náà ni Jesu wí fún wọn pé, “Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, bí kò ṣe pé ẹ̀yin bá jẹ ara ọmọ ènìyàn, kí ẹ sì mu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ẹ̀yin kò ní ìyè nínú yin. Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ara mi, tí ó bá sì mu ẹ̀jẹ̀ mi, ó ní ìyè tí kò nípẹ̀kun; Èmi o sì jí i dìde níkẹyìn ọjọ́. Nítorí ara mi ni ohun jíjẹ nítòótọ́, àti ẹ̀jẹ̀ mi ni ohun mímu nítòótọ́. Ẹni tí ó bá jẹ ara mi, tí ó bá sì mu ẹ̀jẹ̀ mi, ó ń gbé inú mi, èmi sì ń gbé inú rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí Baba alààyè ti rán mi, tí èmi sì yè nípa Baba gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó jẹ mí, òun pẹ̀lú yóò yè nípa mi. Èyí sì ni oúnjẹ náà tí ó sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá: kì í ṣe bí àwọn baba yín ti jẹ manna, tí wọ́n sì kú: ẹni tí ó bá jẹ́ oúnjẹ yìí yóò yè láéláé.” Nǹkan wọ̀nyí ni ó sọ nínú Sinagọgu, bí ó ti ń kọ́ni ní Kapernaumu.