Johanu 21:15-20

Johanu 21:15-20 YCB

Ǹjẹ́ lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n jẹun òwúrọ̀ tan, Jesu wí fún Simoni Peteru pé, “Simoni, ọmọ Jona, ìwọ fẹ́ mi ju àwọn wọ̀nyí lọ bí?” Ó sì wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa; ìwọ mọ̀ pé, mo fẹ́ràn rẹ.” Ó wí fún un pé, “Máa bọ́ àwọn àgùntàn mi.” Ó tún wí fún un nígbà kejì pé, “Simoni ọmọ Jona, ìwọ fẹ́ mi bí?” Ó wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa; ìwọ mọ̀ pé, mo fẹ́ràn rẹ.” Ó wí fún un pé, “Máa bọ́ àwọn àgùntàn mi.” Ó wí fún un nígbà kẹta pé, “Simoni, ọmọ Jona, ìwọ fẹ́ràn mi nítòótọ́ bí?” Inú Peteru sì bàjẹ́, nítorí tí ó wí fún un nígbà ẹ̀kẹta pé, “Ìwọ fẹ́ràn mi nítòótọ́ bí?” Ó sì wí fún un pé, “Olúwa, ìwọ mọ ohun gbogbo; ìwọ mọ̀ pé, mo fẹ́ràn rẹ.” Jesu wí fún un pé, “Máa bọ́ àwọn àgùntàn mi. Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, nígbà tí ìwọ wà ní ọ̀dọ́mọdé, ìwọ a máa di ara rẹ ní àmùrè, ìwọ a sì máa rìn lọ sí ibi tí ìwọ bá fẹ́: ṣùgbọ́n nígbà tí ìwọ bá di arúgbó, ìwọ yóò na ọwọ́ rẹ jáde, ẹlòmíràn yóò sì dì ọ́ ní àmùrè, yóò mú ọ lọ sí ibi tí ìwọ kò fẹ́.” Jesu wí èyí, ó fi ń ṣe àpẹẹrẹ irú ikú tí yóò fi yin Ọlọ́run lógo. Lẹ́yìn ìgbà tí ó sì ti wí èyí tan, ó wí fún un pé, “Máa tọ̀ mí lẹ́yìn.” Peteru sì yípadà, ó rí ọmọ-ẹ̀yìn náà, ẹni tí Jesu fẹ́ràn, ń bọ̀ lẹ́yìn; ẹni tí ó gbara le súnmọ́ àyà rẹ̀ nígbà oúnjẹ alẹ́ tí ó sì wí fún un pé, “Olúwa, ta ni ẹni tí yóò fi ọ́ hàn?”