Nítorí náà, nígbà tí àjọ ìrékọjá ku ọjọ́ mẹ́fà, Jesu wá sí Betani, níbi tí Lasaru wà, ẹni tí ó ti kú, tí Jesu jí dìde kúrò nínú òkú. Wọ́n sì ṣe àsè alẹ́ fún un níbẹ̀: Marta sì ń ṣe ìránṣẹ́: ṣùgbọ́n Lasaru Jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn tí ó jókòó níbi tábìlì rẹ̀. Nígbà náà ni Maria mú òróró ìkunra nadi, òṣùwọ̀n lítà kan, àìlábùlà, olówó iyebíye, ó sì ń fi kun Jesu ní ẹsẹ̀, ó sì ń fi irun orí rẹ̀ nu ẹsẹ̀ rẹ̀ nù. Ilé sì kún fún òórùn ìkunra náà.
Nígbà náà ni ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, Judasi Iskariotu, ọmọ Simoni ẹni tí yóò fi í hàn, wí pé, “Èéṣe tí a kò ta òróró ìkunra yìí ní ọ̀ọ́dúnrún owó idẹ kí a sì fi fún àwọn tálákà?” Ṣùgbọ́n ó wí èyí, kì í ṣe nítorí tí ó náání àwọn tálákà; ṣùgbọ́n nítorí tí ó jẹ́ olè, òun ni ó ni àpò, a sì máa jí ohun tí a fi sínú rẹ̀ láti fi ran ara rẹ lọ́wọ́.
Nígbà náà ni Jesu wí pé, “Ẹ fi í sílẹ̀, ó ṣe é sílẹ̀ de ọjọ́ ìsìnkú mi. Nígbà gbogbo ni ẹ̀yin sá à ní tálákà pẹ̀lú yín; ṣùgbọ́n èmi ni ẹ kò ní nígbà gbogbo.”
Nítorí náà, ìjọ ènìyàn nínú àwọn Júù ni ó mọ̀ pé ó wà níbẹ̀; wọ́n sì wá, kì í ṣe nítorí Jesu nìkan, ṣùgbọ́n kí wọn lè rí Lasaru pẹ̀lú, ẹni tí ó ti jí dìde kúrò nínú òkú. Ṣùgbọ́n àwọn olórí àlùfáà gbìmọ̀ kí wọn lè pa Lasaru pẹ̀lú; Nítorí pé nípasẹ̀ rẹ̀ ni ọ̀pọ̀ nínú àwọn Júù jáde lọ, wọ́n sì gbà Jesu gbọ́.
Ní ọjọ́ kejì nígbà tí ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ó wá sí àjọ gbọ́ pé, Jesu ń bọ̀ wá sí Jerusalẹmu. Wọ́n mú imọ̀ ọ̀pẹ, wọ́n sì jáde lọ pàdé rẹ̀, wọ́n sì ń kígbe pé,
“Hosana!”
“Olùbùkún ni ẹni tí ń bọ̀ wá ní orúkọ Olúwa!”
“Olùbùkún ni ọba Israẹli!”
Nígbà tí Jesu sì rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan, ó gùn ún; gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé pé,
“Má bẹ̀rù, ọmọbìnrin Sioni;
Wò ó, ọba rẹ ń bọ̀ wá,
o jókòó lórí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.”
Nǹkan wọ̀nyí kò tètè yé àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀: ṣùgbọ́n nígbà tí a ṣe Jesu lógo, nígbà náà ni wọ́n rántí pé, a kọ̀wé nǹkan wọ̀nyí nípa rẹ̀ sí i.
Nítorí náà, ìjọ ènìyàn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ nígbà tí o pé Lasaru jáde nínú ibojì rẹ̀, tí ó sì jí i dìde kúrò nínú òkú, jẹ́rìí sí i. Nítorí èyí ni ìjọ ènìyàn sì ṣe lọ pàdé rẹ̀, nítorí tí wọ́n gbọ́ pé ó ti ṣe iṣẹ́ ààmì yìí. Nítorí náà àwọn Farisi wí fún ara wọn pé, “Ẹ kíyèsi bí ẹ kò ti lè borí ní ohunkóhun? Ẹ wo bí gbogbo ayé ti ń wọ́ tọ̀ ọ́!”