Nígbà tí Jesu rí i, tí ó ń sọkún, àti àwọn Júù tí ó bá a wá ń sọkún pẹ̀lú rẹ̀, ó kérora nínú ẹ̀mí, inú rẹ̀ sì bàjẹ́. Ó sì wí pé, “Níbo ni ẹ̀yin gbé tẹ́ ẹ sí?” Wọ́n sì wí fún un pé, “Olúwa, wá wò ó.” Jesu sọkún. Nítorí náà àwọn Júù wí pé, “Sá wò ó bí ó ti fẹ́ràn rẹ̀ tó!” Àwọn kan nínú wọn sì wí pé, “Ọkùnrin yìí, ẹni tí ó la ojú afọ́jú, kò lè ṣe é kí ọkùnrin yìí má kú bí?” Nígbà náà ni Jesu tún kérora nínú ara rẹ̀, ó wá sí ibojì, ó sì jẹ́ ihò, a sì gbé òkúta lé ẹnu rẹ̀.
Kà Johanu 11
Feti si Johanu 11
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Johanu 11:33-38
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò