Onidajọ 6:28-35

Onidajọ 6:28-35 YCB

Nígbà tí ilẹ̀ ọjọ́ kejì mọ́, tí àwọn ènìyàn ìlú náà jí, wọ́n rí i pé àti fọ́ pẹpẹ Baali àti pé a ti bẹ́ igi ère òrìṣà Aṣerah tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, a sì ti fi akọ màlúù kejì rú ẹbọ lórí pẹpẹ tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ. Àwọn ènìyàn ìlú náà bi ara wọn wí pé, “Ta ni ó ṣe èyí?” Lẹ́yìn tí wọn fi ara balẹ̀ ṣe ìwádìí, wọ́n gbọ́ wí pé, “Gideoni ọmọ Joaṣi ni ó ṣe é.” Àwọn ọkùnrin ìlú náà sì wí fún Joaṣi wí pé, “Mú ọmọ rẹ jáde wá. Ó ní láti kú nítorí pé ó ti wó pẹpẹ Baali lulẹ̀ ó sì ti ké ère òrìṣà Aṣerah tí ó wà ní ẹ̀bá rẹ̀ lulẹ̀.” Ṣùgbọ́n Joaṣi bi àwọn èrò tí wọ́n fi ìbínú dúró tì í wí pé, “Ẹ̀yin yóò ha gbìjà Baali bí? Ẹ̀yin yóò ha gbà á sílẹ̀ bí? Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbìjà rẹ̀ kíkú ni olúwa rẹ̀ yóò kú ní òwúrọ̀. Bí Baali bá ṣe Ọlọ́run nítòótọ́ yóò jà fún ara rẹ̀ bí ẹnikẹ́ni bá wó pẹpẹ rẹ̀ lulẹ̀.” Fún ìdí èyí ní ọjọ́ náà wọ́n pe Gideoni ní “Jerubbaali” wí pé, “Jẹ́ kí Baali bá a jà,” nítorí pé ó ti wó pẹpẹ Baali. Láìpẹ́ jọjọ, àwọn ogun àwọn Midiani, ti àwọn Amaleki àti ti àwọn ènìyàn ìhà ìlà-oòrùn yòókù kó ara wọn jọ pọ̀ ní ìṣọ̀kan, wọ́n sì kọjá Jordani wọ́n sì tẹ̀dó sí Àfonífojì Jesreeli. Ẹ̀mí OLúWA sì bà lé Gideoni, ó sì fun fèrè ìpè, láti pe àwọn ará Abieseri láti tẹ̀lé òun. Ó rán àwọn oníṣẹ́ la ilẹ̀ Manase já pé kí wọ́n dira ogun, àti sí Aṣeri, Sebuluni àti Naftali gbogbo pẹ̀lú sì lọ láti pàdé wọn.