Onidajọ 6:17-24

Onidajọ 6:17-24 YCB

Gideoni sì dáhùn pé, nísinsin yìí tí mo bá bá ojúrere rẹ pàdé, fún mi ní ààmì pé ìwọ ni ń bá mi sọ̀rọ̀. Jọ̀wọ́ má ṣe kúrò níbí títí èmi yóò fi mú ọrẹ wá fún ọ kí n sì gbé e sí iwájú rẹ. OLúWA sì wí pé, “Èmi yóò dúró títí ìwọ yóò fi dé.” Gideoni sì yára wọ ilé lọ, ó sì pa ọ̀dọ́ ewúrẹ́ kan, wọ́n sì sè é, ó sì mú ìyẹ̀fun efa kan, ó fi ṣe àkàrà aláìwú. Ó gbé ẹran náà sínú agbọ̀n, ṣùgbọ́n ó fi ọbẹ̀ rẹ̀ sínú ìkòkò, ó gbé wọn jáde tọ angẹli náà wá bí ọrẹ lábẹ́ igi óákù. Angẹli Ọlọ́run náà sì wí fún un pé, “Gbé ẹran náà àti àkàrà àìwú náà, sí orí àpáta yìí, kí o sì da omi ọbẹ̀ rẹ̀ sí orí rẹ̀.” Gideoni sì ṣe bẹ́ẹ̀. Angẹli OLúWA sì fi orí ọ̀pá tí ó wà ní ọwọ́ rẹ̀ kan ẹran àti àkàrà àìwú náà. Iná sì jáde láti inú àpáta, ó sì jó ẹran àti àkàrà náà, kò sì rí angẹli náà mọ́. Nígbà tí Gideoni sì ti mọ̀ dájúdájú pé angẹli OLúWA ni, ó ké wí pé, “Háà! OLúWA Olódùmarè! Mo ti rí angẹli OLúWA ní ojúkorojú!” Ṣùgbọ́n OLúWA wí fún un pé, “Àlàáfíà! Má ṣe bẹ̀rù, ìwọ kì yóò kùú.” Báyìí ni Gideoni mọ pẹpẹ kan fún OLúWA níbẹ̀, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní “Àlàáfíà ni OLúWA.” Ó sì wà ní Ofira ti Abieseri títí di òní.