Isaiah 38:1-8

Isaiah 38:1-8 YCB

Ní ọjọ́ náà ni Hesekiah ṣe àìsàn dé ojú ikú. Wòlíì Isaiah ọmọ Amosi sì lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé, “Ohun tí OLúWA wí nìyìí: Palẹ̀ ilé è rẹ mọ́, bí ó ti yẹ nítorí pé ìwọ yóò kú; ìwọ kì yóò dìde àìsàn yìí.” Hesekiah yí ojú u rẹ̀ sí ara ògiri, ó sì gba àdúrà sí OLúWA, “Rántí, Ìwọ OLúWA, bí mo ti rìn pẹ̀lú òtítọ́ níwájú rẹ, àti bí mo ti fi ọkàn dídúró ṣinṣin ṣe ohun tí ó dára ní ojú ù rẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni Hesekiah sì sọkún kíkorò. Lẹ́yìn náà ni ọ̀rọ̀ OLúWA tọ Isaiah wá pé “Lọ kí o sì sọ fún Hesekiah pé, ‘Ohun tí OLúWA wí nìyìí, Ọlọ́run Dafidi baba rẹ sọ pé: Èmi ti gbọ́ àdúrà rẹ mo sì ti rí omijé rẹ; Èmi yóò fi ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún kún ọjọ́ ayé rẹ. Èmi yóò sì gba ìwọ àti ìlú yìí sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ọba Asiria. Èmi yóò sì dáàbò bo ìlú yìí. “ ‘Èyí yìí ni ààmì tí OLúWA fún ọ láti fihàn wí pé OLúWA yóò mú ìpinnu rẹ̀ ṣẹ: Èmi yóò mú òjìji oòrùn kí ó padà sẹ́yìn ní ìṣísẹ̀ mẹ́wàá nínú èyí tí ó fi sọ̀kalẹ̀ ní ibi àtẹ̀gùn ti Ahasi.’ ” Bẹ́ẹ̀ ni oòrùn padà sẹ́yìn ní ìṣísẹ̀ mẹ́wàá sí ibi tí ó ti dé tẹ́lẹ̀.

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa