Nínú èyí tí Ọlọ́run, ẹni tí ń fẹ́ gidigidi láti fi àìlèyípadà ète rẹ̀ hàn fún àwọn ajogún ìlérí náà, ó fi ìbúra sáàrín wọn. Pé, nípa ohun àìlèyípadà méjì, nínú èyí tí kò le ṣe é ṣe fún Ọlọ́run láti ṣèké, kí a lè mú àwa tí ó ti sá sábẹ́ ààbò rẹ̀ ní ọkàn lè láti di ìrètí tí a gbé kalẹ̀ níwájú wa mú ṣinṣin: Èyí tí àwa níbi ìdákọ̀ró ọkàn fún ọkàn wa, ìrètí tí ó dájú tí ó sì dúró ṣinṣin, tí ó sì wọ inú ilé lọ lẹ́yìn aṣọ ìkélé; níbi tí Jesu, aṣáájú wa ti wọ̀ lọ fún wa, òun sì ni a fi jẹ alábojútó àlùfáà títí láé ní ipasẹ̀ Melkisedeki.
Kà Heberu 6
Feti si Heberu 6
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Heberu 6:17-20
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò