Gẹnẹsisi 5:1-27

Gẹnẹsisi 5:1-27 YCB

Èyí ni àkọsílẹ̀ ìran Adamu. Nígbà tí Ọlọ́run dá ènìyàn, ní àwòrán Ọlọ́run ni ó dá a. Àti akọ àti abo ni Ó dá wọn, ó sì súre fún wọn, ó sì pe orúkọ wọ́n ní Adamu ní ọjọ́ tí ó dá wọn. Nígbà tí Adamu di ẹni àádóje ọdún (130), ó bí ọmọkùnrin kan tí ó jọ ọ́, tí ó jẹ́ àwòrán ara rẹ̀, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Seti. Ọjọ́ Adamu, lẹ́yìn ìgbà tí ó bí Seti, jẹ́ ẹgbẹ̀rin ọdún (800), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. Àpapọ̀ ọdún tí Adamu gbé ní orí ilẹ̀ jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún-ọdún ó-lé-ọgbọ̀n (930), ó sì kú. Nígbà tí Seti pé àrùnlélọ́gọ́rùnún ọdún (105), ó bí Enoṣi. Lẹ́yìn ìgbà tí ó bí Enoṣi, Seti sì gbé fún ẹgbẹ̀rin ó-lé-méje ọdún (807), ó sì bí àwọn; ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. Àpapọ̀ ọdún Seti sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún-ọdún ó-lé-méjìlá (912), ó sì kú. Nígbà tí Enoṣi di ẹni àádọ́rùn-ún ọdún (90) ni ó bí Kenani. Lẹ́yìn tí ó bí Kenani, Enoṣi sì wà láààyè fún ẹgbẹ̀rin ọdún ó-lé-mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (815), ó sì bí àwọn ọkùnrin àti obìnrin. Àpapọ̀ ọdún Enoṣi jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún-ọdún ó-lé-márùn-ún (905), ó sì kú. Nígbà tí Kenani di àádọ́rin ọdún (70) ni ó bí Mahalaleli: Lẹ́yìn tí ó bí Mahalaleli, Kenani wà láààyè fún òjìlélẹ́gbẹ̀rin ọdún (840), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. Àpapọ̀ ọjọ́ Kenani jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ó-lé-mẹ́wàá ọdún (910), ó sì kú. Nígbà tí Mahalaleli pé ọmọ àrùnlélọ́gọ́ta ọdún (65) ni ó bí Jaredi. Mahalaleli sì gbé fún ẹgbẹ̀rin ó-lé-ọgbọ̀n ọdún (830) lẹ́yìn ìgbà tí ó bí Jaredi, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. Àpapọ̀ iye ọdún Mahalaleli jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ̀gbẹ̀rún-ọdún-ó-dín-márùn-ún (895), ó sì kú. Nígbà tí Jaredi pé ọmọ ọgọ́jọ ó-lé-méjì ọdún (162) ni ó bí Enoku. Lẹ́yìn èyí, Jaredi wà láààyè fún ẹgbẹ̀rin ọdún (800) Enoku sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. Àpapọ̀ ọdún Jaredi sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún-dínméjìdínlógójì (962), ó sì kú. Nígbà tí Enoku pé ọmọ ọgọ́ta ó-lé-márùn ọdún (65) ni ó bí Metusela. Lẹ́yìn tí ó bí Metusela, Enoku sì bá Ọlọ́run rìn ní ọ̀ọ́dúnrún ọdún (300), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. Àpapọ̀ ọjọ́ Enoku sì jẹ́ irínwó-dínmárùn-dínlógójì-ọdún (365). Enoku bá Ọlọ́run rìn; a kò sì rí i mọ́ nítorí Ọlọ́run mú un lọ. Nígbà tí Metusela pé igba ó-dínmẹ́tàlá ọdún (187) ní o bí Lameki. Lẹ́yìn èyí Metusela wà láààyè fún ẹgbẹ̀rìn-dínméjì-dínlógún ọdún (782), lẹ́yìn ìgbà tí ó bí Lameki, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. Àpapọ̀ ọdún Metusela jẹ́ ẹgbẹ̀rún ọdún ó-dínmọ́kànlélọ́gbọ̀n (969), ó sì kú.