Gẹnẹsisi 45:1-8

Gẹnẹsisi 45:1-8 YCB

Josẹfu kò sì le è pa á mọ́ra mọ́ níwájú gbogbo àwọn tí ó dúró tì í. Ó sì sọkún sókè tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn tí ó wà ní àyíká gbọ́ ohun ẹkún rẹ̀. “Jẹ́ kí gbogbo ènìyàn kúrò ní ọ̀dọ̀ mi.” Kò sì sí ẹnikẹ́ni lọ́dọ̀ rẹ̀ nígbà tí ó fi ara rẹ̀ hàn fún àwọn arákùnrin rẹ̀. Ó sì sọkún sókè kíkankíkan tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn Ejibiti gbọ́ ohùn ẹkún rẹ̀, àwọn ilé Farao pẹ̀lú sì gbọ́ nípa rẹ̀. Josẹfu wí fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé, “Èmi ni Josẹfu! Ṣe baba mi sì wà láààyè?” Ṣùgbọ́n àwọn arákùnrin rẹ̀ kò le è dá a lóhùn nítorí ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi, ẹnu sì yà wọ́n níwájú rẹ̀. Nígbà náà ni Josẹfu wí fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé, “Ẹ súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi.” Nígbà tí wọ́n sì ti ṣe bẹ́ẹ̀, ó wí pé, “Èmi ni Josẹfu arákùnrin yín tí ẹ tà sí ilẹ̀ Ejibiti! Ṣùgbọ́n báyìí, Ẹ má ṣe banújẹ́, ẹ má sì ṣe bínú sí ara yín ní títà tí ẹ tà mí sí ìhín, nítorí, ọ̀nà àti gba ẹ̀mí yín là ni Ọlọ́run ṣe rán mi sí ìhín ṣáájú yín. Ìyàn tí ó ti mú láti ọdún méjì sẹ́yìn yìí yóò tẹ̀síwájú fún ọdún márùn-ún sí i nínú èyí tí ẹnikẹ́ni kò ní gbìn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ni kórè. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run rán mi ṣáájú yín sí ìhín láti da irú-ọmọ yín sí fún un yín lórí ilẹ̀ ayé àti láti fi ìgbàlà ńlá gba ẹ̀mí yín là. “Nítorí náà kì í ṣe ẹ̀yin ni ó rán mi wá sí ìhín bí kò ṣe Ọlọ́run. Ó fi mí ṣe baba (Olùdámọ̀ràn) fún Farao, olúwa fún gbogbo ilé Farao àti alákòóso gbogbo ilẹ̀ Ejibiti.