Ẹ̀yin aláìnírònú ará Galatia! Ta ní ha tàn yín jẹ, kí ẹ̀yin má ṣe gba òtítọ́ gbọ́? Ní ojú ẹni tí a fi Jesu Kristi hàn gbangba láàrín yín ni ẹni tí a kàn mọ́ àgbélébùú. Kìkì èyí ni mo fẹ́ béèrè lọ́wọ́ yín: Nípa iṣẹ́ òfin ni ẹ̀yin gba Ẹ̀mí bí, tàbí nípa ìgbọ́ràn pẹ̀lú ìgbàgbọ́? Báyìí ni ẹ̀yin ṣe jẹ òmùgọ̀ tó bí? Ẹ̀yin tí ó ti bẹ̀rẹ̀ ìgbé ayé ìgbàgbọ́ yín nípa ti Ẹ̀mí, ṣé a ti wá sọ yín di pípé nípa ti ara ni? Ẹ̀yin ha ti jìyà ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan wọ̀nyí lásán? Bí ó bá ṣe pé nítòótọ́ lásán ni. Ṣé Ọlọ́run fún yín ní Ẹ̀mí rẹ̀, tí ó sì ṣe iṣẹ́ ìyanu láàrín yín nítorí tí ẹ̀yin pa òfin mọ, tàbí nítorí ẹ ní ìgbàgbọ́ sí ohun tí ẹ gbọ́? Gẹ́gẹ́ bí Abrahamu “Ó gba Ọlọ́run gbọ́, a sì kà á sí òdodo fún un.”
Kà Galatia 3
Feti si Galatia 3
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Galatia 3:1-6
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò